Ìfihàn 12:7-17
7
Ogun sì ń bẹ ní ọ̀run: Mikaeli àti àwọn angẹli rẹ̀ bá dragoni náà jagun; dragoni sì jagun àti àwọn angẹli rẹ̀.
8
Wọ́n kò sì lè ṣẹ́gun; bẹ́ẹ̀ ni a kò sì rí ipò wọn mọ́ ni ọ̀run.
9
A sì lé dragoni ńlá náà jáde, ejò láéláé nì, tí a ń pè ni Èṣù, àti Satani, tí ń tan gbogbo ayé jẹ: a sì lé e jù sí ilẹ̀ ayé, a sì lé àwọn angẹli rẹ̀ jáde pẹ̀lú rẹ̀.
10
Mo sì gbọ́ ohùn ńlá ní ọ̀run, wí pè: “Nígbà yìí ni ìgbàlà dé, àti agbára, àti ìjọba Ọlọ́run wá, àti ọlá àti Kristi rẹ̀. Nítorí a tí le olùfisùn àwọn arákùnrin wa jáde, tí o ń fi wọ́n sùn níwájú Ọlọ́run wa lọ́sàn án àti lóru.
11
Wọ́n sì ti ṣẹ́gun rẹ̀ nítorí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-àgùntàn náà, àti nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wọn, wọn kò sì fẹ́ràn ẹ̀mí wọn àní títí dé ikú.
12
Nítorí náà ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn. Ègbé ni fún ayé àti Òkun; nítorí èṣù sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá ní ìbínú ńlá, nítorí ó mọ̀ pé ìgbà kúkúrú sá ni òun ní.”
13
Nígbà tí dragoni náà rí pé a lé òun lọ sí ilẹ̀ ayé, ó ṣe inúnibíni sì obìnrin tí ó bí ọmọkùnrin náà.
14
A sì fi apá ìyẹ́ méjì tí idì ńlá náà fún obìnrin náà, pé kí ó fò lọ sí aginjù, sí ipò rẹ̀, níbi tí a ó gbe bọ ọ fún àkókò kan àti fún àwọn àkókò, àti fún ìdajì àkókò kúrò lọ́dọ̀ ejò náà.
15
Ejò náà sì tu omi jáde láti ẹnu rẹ̀ wá bí odò ńlá sẹ́yìn obìnrin náà, kí ó lè fi ìṣàn omi náà gbà á lọ.
16
Ilẹ̀ sì ran obìnrin náà lọ́wọ́, ilẹ̀ sì ya ẹnu rẹ̀, ó sì fi ìṣàn omi náà mú, tí dragoni náà tu jáde láti ẹnu rẹ̀ wá.
17
Dragoni náà sì bínú gidigidi sí obìnrin náà, ó sì lọ bá àwọn irú-ọmọ rẹ̀ ìyókù jagun, tí wọ́n ń pa òfin Ọlọ́run mọ̀, tí wọn sì di ẹ̀rí Jesu mú, Ó sì dúró lórí iyanrìn Òkun.
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings