Skip to content
Saamu 106:7-31

Saamu 106:7-31

7
Nígbà tí àwọn baba wa wà ní Ejibiti, iṣẹ́ ìyanu rẹ kò yé wọn, wọn kò rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí ọ níbi Òkun, àní níbi Òkun Pupa.
8
Ṣùgbọ́n o gbà wọ́n là nítorí orúkọ rẹ láti jẹ́ kí agbára ńlá rẹ di mí mọ̀.
9
O bá Òkun Pupa wí, ó sì gbẹ; o sì mú wọn la ìbú já bí aginjù.
10
O gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, láti ọwọ́ ọ̀tá ni o ti gbà wọ́n.
11
Omi ya lu àwọn ọ̀tá wọn; bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí ó yè nínú wọn.
12
Nígbà náà wọn gba ìpinnu rẹ gbọ́ wọ́n sì kọrin ìyìn rẹ.
13
Ṣùgbọ́n wọn kò pẹ́ gbàgbé ohun tí o ṣe wọn kò sí dúró gba ìmọ̀ràn rẹ.
14
Nínú aginjù ni wọ́n tí ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, nínú aṣálẹ̀, wọ́n dán Ọlọ́run wò.
15
Nígbà náà, ó fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún ṣùgbọ́n ó rán àìsàn búburú sí wọn.
16
Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mose pẹ̀lú Aaroni, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa.
17
Ilẹ̀ la ẹnu ó sì gbé Datani mì ó bo ẹgbẹ́ Abiramu mọ́lẹ̀.
18
Ọwọ́ iná yọ ní ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; iná jo àwọn ènìyàn búburú.
19
Ní Horebu wọ́n ṣe ẹgbọrọ màlúù wọ́n sì sin òrìṣà tí a ṣe láti ara irin.
20
Wọ́n pa ògo wọn dà sí àwòrán màlúù, tí ń jẹ koríko.
21
Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run, ẹni tí ó gbà wọ́n ẹni tí ó ti ṣe ohun ńlá ní Ejibiti,
22
iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu àti ohun ẹ̀rù ni ẹ̀bá Òkun Pupa.
23
Bẹ́ẹ̀ ni, ó sọ wí pé, òun yóò pa wọ́n run bí kò bá ṣe ti Mose, tí ó yàn, tí ó dúró níwájú ẹ̀yà náà tí ó pa ìbínú rẹ̀ mọ́ láti má pa wọ́n run mọ́.
24
Nígbà náà, wọ́n kẹ́gàn ilẹ̀ dídára náà wọn kò gba ìlérí rẹ̀ gbọ́.
25
Wọ́n ń kùn nínú àgọ́ wọn wọn kò sì gbọ́rọ̀ sí Olúwa.
26
Bẹ́ẹ̀ ni ó búra fún wọn nípa gbígbé ọwọ́ rẹ̀ sókè kí òun lè jẹ́ kí wọn ṣubú nínú aginjù,
27
láti jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣubú lára orílẹ̀-èdè láti fọ́n wọn káàkiri lórí ilẹ̀.
28
Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali-Peori, wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí a rú sí àwọn òkú òrìṣà,
29
wọ́n mú Ọlọ́run bínú pẹ̀lú ohun búburú tí wọn ń ṣe àjàkálẹ̀-ààrùn jáde láàrín wọn.
30
Ṣùgbọ́n Finehasi dìde láti dá sí i, àjàkálẹ̀-ààrùn náà sì dáwọ́ dúró lọ́gán.
31
A sì ka èyí sí òdodo fún un àti fún àwọn ìrandíran tí ń bọ̀
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options