Skip to content
Numeri 32:33-38

Numeri 32:33-38

33
Nígbà náà Mose fún àwọn ọmọ Gadi àti àwọn ọmọ Reubeni àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase ọmọ Josẹfu ní ilẹ̀ ọba Sihoni ọba àwọn ọmọ Amori àti ilẹ̀ ọba Ogu ọba Baṣani ní gbogbo ilẹ̀ náà pẹ̀lú ìlú rẹ̀ àti agbègbè tí ó yí i ka.
34
Àwọn ará Gadi wọ́n kọ́ Diboni, Atarotu, Aroeri;
35
pẹ̀lú Atrotu Ṣofani, Jaseri, àti Jogbeha,
36
pẹ̀lú Beti-Nimra, àti Beti-Harani ìlú olódi, àti agbo fún àgùntàn.
37
Àwọn ọmọ Reubeni sì kọ́ Heṣboni, Eleale, Kiriataimu,
38
pẹ̀lú Nebo pẹ̀lú Baali-Meoni (wọ́n pàrọ̀ orúkọ wọn) àti Sibma. Wọ́n sì sọ ìlú tí wọ́n tún kọ́ ní orúkọ mìíràn.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options