Numeri 10:11-28
11
Ní ogúnjọ́ oṣù kejì, ní ọdún kejì ni ìkùùkuu kúrò lórí tabanaku ẹ̀rí.
12
Àwọn ọmọ Israẹli sì gbéra kúrò ní aginjù Sinai wọ́n sì rin ìrìnàjò wọn káàkiri títí tí ìkùùkuu fi dúró sí aginjù Parani.
13
Wọ́n gbéra nígbà àkọ́kọ́ yìí nípa àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose.
14
Àwọn ìpín ti ibùdó Juda ló kọ́kọ́ gbéra tẹ̀lé wọn lábẹ́ ogun wọn Nahiṣoni ọmọ Amminadabu ni ọ̀gágun wọn.
15
Netaneli ọmọ Suari ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Isakari;
16
Eliabu ọmọ Heloni ni ọ̀gágun ni ìpín ti ẹ̀yà Sebuluni.
17
Nígbà náà ni wọ́n sọ tabanaku kalẹ̀ àwọn ọmọ Gerṣoni àti Merari tó gbé àgọ́ sì gbéra.
18
Àwọn ìpín ti ibùdó ti Reubeni ló gbéra tẹ̀lé wọn, lábẹ́ ọ̀págun wọn. Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni ọ̀gágun wọn.
19
Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Simeoni.
20
Eliasafu ọmọ Deueli ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Gadi.
21
Nígbà náà ni àwọn ọmọ Kohati tí ń ru ohun mímọ́ náà gbéra. Àwọn ti àkọ́kọ́ yóò sì ti gbé tabanaku dúró kí wọn tó dé.
22
Àwọn ìpín tó wà ní ibùdó Efraimu ló tún kàn lábẹ́ ọ̀págun wọn. Eliṣama ọmọ Ammihudu ni ọ̀gágun wọn.
23
Gamalieli ọmọ Pedasuri ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Manase.
24
Abidani ọmọ Gideoni ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Benjamini.
25
Lákòótan, àwọn ọmọ-ogun tó ń mójútó ẹ̀yìn ló tún kàn, àwọn ni ìpín ti ibùdó Dani lábẹ́ ọ̀págun wọn. Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai ni ọ̀gágun wọn.
26
Pagieli ọmọ Okanri ni ìpín ti ẹ̀yà Aṣeri,
27
Ahira ọmọ Enani ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Naftali.
28
Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe tò jáde gẹ́gẹ́ bí ogun nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn.
Settings