Nehemiah 3:15-27
15
Ẹnu ibodè orísun ni Ṣalluni Koli-Hose, alákòóso agbègbè Mispa tún mọ. Ó tún ún mọ, ó kan òrùlé e rẹ̀ yíká, ó gbé àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn idẹ rẹ̀ ró sí ààyè wọn. Ó tún tún odi adágún Siloamu mọ, ní ẹ̀gbẹ́ ọgbà ọba, títí dé àwọn àtẹ̀gùn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ láti ìlú Dafidi.
16
Lẹ́yìn in rẹ̀ ni, Nehemiah ọmọ Asbuku, alákòóso ìdajì agbègbè Beti-Suri ṣe àtúnmọ dé ibi ọ̀ọ́kán òdìkejì ibojì Dafidi, títí dé adágún omi àtọwọ́dá àti títí dé ilé àwọn alágbára.
17
Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn ará a Lefi, ní abẹ́ ẹ Rehumu ọmọ Bani. Lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni Haṣabiah, alákòóso ìdajì agbègbè Keila ṣe àtúnṣe fún agbègbè tirẹ̀.
18
Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn Lefi arákùnrin wọn ní abẹ́ àkóso Binnui ṣe àtúnṣe, Bafai ọmọ Henadadi, ìjòyè àwọn ìdajì agbègbè Keila.
19
Lẹ́yìn rẹ̀ ni Eseri ọmọ Jeṣua, alákòóso Mispa, tún ìbò mìíràn ṣe, láti ibìkan tí ó kojú sí ibi gíga sí ilé-ìhámọ́ra títí dé orígun.
20
Lẹ́yìn rẹ̀ ni Baruku ọmọ Sakkai fi ìtara tún apá mìíràn ṣe, láti orígun dé ẹnu-ọ̀nà ilé Eliaṣibu olórí àlùfáà.
21
Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Meremoti ọmọ Uriah, ọmọ Hakosi tún apá mìíràn ṣe, láti ẹnu-ọ̀nà ilé Eliaṣibu títí dé òpin rẹ̀.
22
Àtúnṣe tí a tún túnṣe lẹ́yìn rẹ̀ ní àwọn àlùfáà ní àyíká agbègbè túnṣe.
23
Lẹ́yìn wọn ni Benjamini àti Haṣubu tún èyí ti iwájú ilé wọn ṣe; lẹ́yìn wọn ni, Asariah ọmọ Maaseiah ọmọ Ananiah tún ti ẹ̀gbẹ́ ilé rẹ̀ ṣe.
24
Lẹ́yìn rẹ̀ ni Binnui ọmọ Henadadi tún apá mìíràn ṣe, láti ilé Asariah dé orígun àti kọ̀rọ̀,
25
àti Palali ọmọ Usai tún òdìkejì orígun ṣe àti ilé ìṣọ́ tí ó yọ sóde láti ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ààfin ọba ti òkè lẹ́gbẹ̀ẹ́ agbègbè àwọn olùṣọ́. Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Pedaiah ọmọ Paroṣi
26
àti àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili tí ó ń gbé ní òkè Ofeli ṣe àtúnṣe títí dé ibi ọ̀kánkán òdìkejì ibodè omi sí ìhà ìlà-oòrùn àti ilé ìṣọ́ tí ó yọ sóde.
27
Lẹ́yìn wọn ni àwọn ènìyàn Tekoa tún apá mìíràn ṣe, láti ilé ìṣọ́ ńlá tí ó yọ sóde títí dé ògiri Ofeli.
Settings