Skip to content
Nehemiah 3:28-32

Nehemiah 3:28-32

28
Àwọn àlùfáà ni ó ṣe àtúnṣe òkè ibodè ẹṣin ṣe, ẹnìkọ̀ọ̀kan ní iwájú ilé e rẹ̀.
29
Lẹ́yìn wọn, Sadoku ọmọ Immeri tún ọ̀kánkán òdìkejì ilé rẹ̀ ṣe. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Ṣemaiah ọmọ Ṣekaniah, olùṣọ́ ibodè ìhà ìlà-oòrùn ṣe àtúnṣe.
30
Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Hananiah ọmọ Ṣelemiah, àti Hanuni ọmọ ẹ̀kẹfà Salafi, tún apá ibòmíràn ṣe. Lẹ́yìn wọn ni, Meṣullamu ọmọ Berekiah tún ọ̀kánkán òdìkejì ibùgbé ẹ̀ ṣe.
31
Lẹ́yìn in rẹ̀ ni Malkiah, ọ̀kan nínú àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà ṣe àtúnṣe títí dé ilé àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn oníṣòwò, ní ọ̀kánkán òdìkejì ibodè àyẹ̀wò títí dé yàrá òkè kọ̀rọ̀;
32
àti láàrín yàrá òkè kọ̀rọ̀ àti ibodè àgùntàn ni àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà àti àwọn oníṣòwò túnṣe.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options