Nahumu 3:1-13
1
Ègbé ni fún ìlú ẹ̀jẹ̀ nì, gbogbo rẹ̀ kún fún èké, ó kún fún olè, ìjẹ kò kúrò!
2
Ariwo pàṣán àti ariwo kíkùn kẹ̀kẹ́ ogun àti jíjó ẹṣin àti gbígbọn kẹ̀kẹ́ ogun jìgìjìgì!
3
Ológun orí ẹṣin ń fi ìgbónára ju idà wọn mọ̀nàmọ́ná ọ̀kọ̀ rẹ̀ ti ń dán yanran sí òkè! Ọ̀pọ̀lọpọ̀ si ní àwọn ẹni tí a pa, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkú; òkú kò sì ni òpin; àwọn ènìyàn sì ń kọsẹ̀ lára àwọn òkú.
4
Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ panṣágà àgbèrè tí ó rójú rere gbà, ìyá àjẹ́ tí ó ṣọ́ àwọn Orílẹ̀-èdè di ẹrú nípa àgbèrè rẹ̀ àti àwọn ìdílé nípa ìṣe àjẹ́ rẹ̀.
5
“Èmi dojúkọ ọ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Èmi ó si ká aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ ní ojú rẹ. Èmi yóò sì fi ìhòhò rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè àti ìtìjú rẹ̀ han àwọn ilẹ̀ ọba.
6
Èmi yóò da ẹ̀gbin tí ó ni ìríra sí ọ ní ara, èmi yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹlẹ́yà.
7
Gbogbo àwọn tí ó ba sì wò ọ́ yóò sì káàánú fún ọ, wọn yóò sì wí pé, ‘Ninefe ṣòfò, ta ni yóò kẹ́dùn rẹ?’ Níbo ni èmi o ti wá olùtùnú fún ọ?”
8
Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn ju Tebesi lọ, èyí tí ó wà ní ibi odò Naili, tí omi sì yí káàkiri? Odò náà sì jẹ́ ààbò rẹ̀, omi si jẹ́ odi rẹ̀.
9
Etiopia àti Ejibiti ni agbára rẹ, kò sí ní òpin; Puti àti Libia ni àwọn olùgbèjà rẹ̀.
10
Síbẹ̀síbẹ̀ a kó o ní ìgbèkùn o sì lọ sí oko ẹrú. Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ̀ ni a ó fọ́ mọ́lẹ̀ ní orí ìta gbogbo ìgboro. Wọ́n sì di ìbò nítorí àwọn ọlọ́lá rẹ̀ ọkùnrin, gbogbo àwọn ọlọ́lá rẹ ni a sì fi ẹ̀wọ̀n dè.
11
Ìwọ pẹ̀lú yóò sì mu àmupara; a ó sì fi ọ́ pamọ́ ìwọ pẹ̀lú yóò máa ṣe àfẹ́rí ààbò nítorí ti ọ̀tá náà.
12
Gbogbo ilé ìṣọ́ agbára rẹ yóò dàbí igi ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú àkọ́pọ́n èso wọn; nígbà tí wọ́n bá ń gbọ̀n wọ́n, ọ̀pọ̀tọ́ yóò sì bọ́ sí ẹnu àwọn ọ̀jẹun.
13
Kíyèsi gbogbo àwọn jagunjagun! Obìnrin ni gbogbo wọn. Ojú ibodè rẹ ní a ó ṣí sílẹ̀ gbagada, fún àwọn ọ̀tá rẹ; iná yóò jó ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ibodè rẹ.
Settings