Skip to content
Mika 6:1-8

Mika 6:1-8

1
Ẹ fi etí sí ohun tí Olúwa wí: “Dìde dúró, bẹ ẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ rẹ níwájú òkè ńlá; sì jẹ́ kí àwọn òkè kéékèèké gbọ́ ohun tí ó fẹ́ wí.
2
“Gbọ́, ìwọ òkè ńlá, ẹ̀sùn Olúwa; gbọ́, ìwọ ìpìlẹ̀ ilé ayérayé. Nítorí Olúwa ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wíjọ́; òun yóò sì bá Israẹli rojọ́.
3
“Ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ni mo ṣe fún yín? Àti nínú kí ni mo ti dá yin lágara? Dá mi lóhùn.
4
Nítorí èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá, mo sì rà yín padà láti ilẹ̀ ẹrú wá. Mo rán Mose láti darí yín, bákan náà mo rán Aaroni àti Miriamu síwájú rẹ̀.
5
Ìwọ ènìyàn mi, rántí ohun tí Balaki ọba Moabu gbèrò àti ohun tí Balaamu ọmọ Beori dáhùn. Rántí ìrìnàjò rẹ̀ láti Ṣittimu dé Gilgali, kí ìwọ ba le mọ òdodo Olúwa.”
6
Kí ni èmi yóò ha mú wá síwájú Olúwa tí èmi ó fi tẹ ara mi ba níwájú Ọlọ́run gíga? Kí èmi ha wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, pẹ̀lú ọmọ màlúù ọlọ́dún kan?
7
Ǹjẹ́ Olúwa yóò ní inú dídùn sí ẹgbẹgbàarùn-ún àgbò, tàbí sí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ìṣàn òróró? Èmi yóò ha fi àkọ́bí mi sílẹ̀ fún ìré-òfin-kọjá mi, èso inú ara mi fún ẹ̀ṣẹ̀ ọkàn mi?
8
Ó ti fihàn ọ́, ìwọ ènìyàn, ohun tí ó dára, àti ohun tí Olúwa ń béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe láti ṣe òtítọ́, kí o sì fẹ́ràn àánú, àti kí o rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options