Luku 22:7-20
7
Ọjọ́ àìwúkàrà pé, nígbà tí wọ́n ní láti pa ọ̀dọ́-àgùntàn ìrékọjá fún ìrúbọ.
8
Ó sì rán Peteru àti Johanu, wí pé, “Ẹ lọ pèsè ìrékọjá fún wa, kí àwa ó jẹ.”
9
Wọ́n sì wí fún un pé, “Níbo ni ìwọ ń fẹ́ kí á pèsè sílẹ̀?”
10
Ó sì wí fún wọn pé, “Kíyèsi i, nígbà tí ẹ̀yin bá ń wọ ìlú lọ, ọkùnrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóò pàdé yín, ẹ bá a lọ sí ilé tí ó bá wọ̀,
11
kí ẹ sì wí fún baálé ilé náà pé, ‘Olùkọ́ wí fún ọ pé, níbo ni gbàngàn àpèjẹ náà gbé wà, níbi tí èmi ó gbé jẹ ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’
12
Òun ó sì fi gbàngàn ńlá kan lókè ilé hàn yín, tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin pèsè sílẹ̀.”
13
Wọ́n sì lọ wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó tí sọ fún wọn, wọ́n sì pèsè ìrékọjá sílẹ̀.
14
Nígbà tí àkókò sì tó, ó jókòó àti àwọn aposteli pẹ̀lú rẹ̀.
15
Ó sì wí fún wọn pé, “Tinútinú ni èmi fẹ́ fi bá yín jẹ ìrékọjá yìí, kí èmi tó jìyà.
16
Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò jẹ nínú rẹ̀ mọ́, títí a ó fi mú un ṣẹ ní ìjọba Ọlọ́run.”
17
Ó sì gba ago, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó wí pé, “Gba èyí, kí ẹ sì pín in láàrín ara yín.
18
Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò mu nínú èso àjàrà mọ́, títí ìjọba Ọlọ́run yóò fi dé.”
19
Ó sì mú àkàrà, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́ ó bù ú, ó sì fi fún wọn, ó wí pé, “Èyí ni ara mí tí a fi fún yín, ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”
20
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú ago wáìnì, ó wí pé, “Ago yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, tí a ta sílẹ̀ fún yín.
Settings