Luku 19:14-38
14
“Ṣùgbọ́n àwọn ará ìlù rẹ̀ kórìíra rẹ̀, wọ́n sì rán ikọ̀ tẹ̀lé e, wí pé, ‘Àwa kò fẹ́ kí ọkùnrin yìí jẹ ọba lórí wa.’
15
“Nígbà tí ó gba ìjọba tan, tí ó padà dé, ó pàṣẹ pé, kí a pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ wọ̀nyí tí òun ti fi owó fún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí kí ó le mọ iye èrè tí olúkúlùkù ti jẹ nínú iṣẹ́ òwò wọn.
16
“Èyí èkínní sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mina rẹ jèrè owó mina mẹ́wàá sí i.’
17
“Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere! Nítorí tí ìwọ ṣe olóòtítọ́ ní ohun kínkínní, gba àṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá.’
18
“Èyí èkejì sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mina rẹ jèrè owó mina márùn.’
19
“Olúwa rẹ sì wí fún un pẹ̀lú pé, ‘Ìwọ pẹ̀lú joyè ìlú márùn-ún!’
20
“Òmíràn sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, wò ó owó mina rẹ tí ń bẹ lọ́wọ́ mi ni mo dì sínú aṣọ pélébé kan;
21
nítorí mo bẹ̀rù rẹ, àti nítorí tí ìwọ ṣe òǹrorò ènìyàn, ìwọ a máa mú èyí tí ìwọ kò fi lélẹ̀, ìwọ a sì máa ká èyí tí ìwọ kò gbìn!’
22
“Olúwa rẹ sì wí fún un pé, ‘Ní ẹnu ara rẹ náà ni èmi ó ṣe ìdájọ́ rẹ, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé òǹrorò ènìyàn ni mí, pé, èmi a máa mú èyí tí èmi kò fi lélẹ̀ èmi a sì máa ká èyí tí èmi kò gbìn.
23
Èéha sì ti ṣe tí ìwọ kò fi owó mi pamọ́ sí ilé ìfowópamọ́, pé nígbà tí mo bá dé, èmi ìbá ti béèrè rẹ̀ pẹ̀lú èlé?’
24
“Ó sì wí fún àwọn tí ó dúró létí ibẹ̀ pé, ‘Ẹ gba owó mina náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì fi í fún ẹni tí ó ní owó mina mẹ́wàá.’
25
“Wọ́n sì wí fún un pé, ‘Olúwa, ó ní owó mina mẹ́wàá.’
26
“Mo wí fún yín pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní, ni a ó fi fún, àti lọ́dọ̀ ẹni tí kò ní èyí tí ó ní pàápàá a ó gbà á lọ́wọ́ rẹ̀.
27
Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá mi wọ̀nyí, tí kò fẹ́ kí èmi jẹ ọba lórí wọn ẹ mú wọn wá ìhín yìí, kí ẹ sì pa wọ́n níwájú mi!’ ”
28
Nígbà tí ó sì ti wí nǹkan wọ̀nyí tan, ó lọ síwájú, ó ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu.
29
Ó sì ṣe, nígbà tí ó súnmọ́ Betfage àti Betani ní òkè tí a ń pè ní òkè olifi, ó rán àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
30
Wí pé, “Ẹ lọ sí ìletò tí ó kọjú sí yín; nígbà tí ẹ̀yin bá wọ̀ ọ́ lọ, ẹ̀yin ó rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí a so, tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí, ẹ tú u, kí ẹ sì fà á wá.
31
Bí ẹnikẹ́ni bá sì bi yín pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tú u?’ Kí ẹ̀yin wí báyìí pé, ‘Olúwa ń fẹ́ lò ó.’ ”
32
Àwọn tí a rán sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó ti wí fún wọn.
33
Bí wọ́n sì ti ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn Olúwa rẹ̀ bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà?”
34
Wọ́n sì wí pé, “Olúwa fẹ́ lò ó.”
35
Wọ́n sì fà á tọ Jesu wá, wọ́n sì tẹ́ aṣọ sí ẹ̀yìn ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, wọ́n sì gbé Jesu kà á.
36
Bí ó sì ti ń lọ wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà.
37
Bí ó sì ti súnmọ́ etí ibẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olifi, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀, wọ́n sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run, nítorí iṣẹ́ ńlá gbogbo tí wọ́n ti rí,
38
wí pé, “Olùbùkún ni ọba tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa!” “Àlàáfíà ní ọ̀run, àti ògo ni òkè ọ̀run!”
Settings