Skip to content
Luku 1:39-56

Luku 1:39-56

39
Ní àkókò náà ni Maria sì dìde, ó lọ kánkán sí ilẹ̀ òkè, sí ìlú kan ní Judea;
40
Ó sì wọ ilé Sekariah lọ ó sì kí Elisabeti.
41
Ó sì ṣe, nígbà tí Elisabeti gbọ́ kíkí Maria, ọlẹ̀ sọ nínú rẹ̀; Elisabeti sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́,
42
Ó sì ké ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Alábùkún fún ni ìwọ nínú àwọn obìnrin, alábùkún fún sì ni ọmọ tí ìwọ yóò bí.
43
Èéṣe tí èmi fi rí irú ojúrere yìí, tí ìyá Olúwa mi ìbá fi tọ̀ mí wá?
44
Sá wò ó, bí ohùn kíkí rẹ ti bọ́ sí mi ní etí, ọlẹ̀ sọ nínú mi fún ayọ̀.
45
Alábùkún fún sì ni ẹni tí ó gbàgbọ́, nítorí nǹkan wọ̀nyí tí a ti sọ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò ṣẹ.”
46
Maria sì dáhùn, ó ní: “Ọkàn mi yin Olúwa lógo.
47
Ẹ̀mí mi sì yọ̀ sí Ọlọ́run Olùgbàlà mi.
48
Nítorí tí ó síjú wo ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ọmọbìnrin ọ̀dọ̀ rẹ̀. Sá wò ó, láti ìsinsin yìí lọ gbogbo ìran ènìyàn ni yóò máa pè mí ní alábùkún fún.
49
Nítorí ẹni tí ó ní agbára ti ṣe ohun tí ó tóbi fún mi; Mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀.
50
Àánú rẹ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, láti ìrandíran.
51
Ó ti fi agbára hàn ní apá rẹ̀; o ti tú àwọn onígbèéraga ká ní ìrònú ọkàn wọn.
52
Ó ti mú àwọn alágbára kúrò lórí ìtẹ́ wọn, o sì gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ lékè.
53
Ó ti fi ohun tí ó dára kún àwọn tí ebi ń pa ó sì rán àwọn ọlọ́rọ̀ padà ní òfo.
54
Ó ti ran Israẹli ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́, ní ìrántí àánú rẹ̀;
55
sí Abrahamu àti àwọn ìran rẹ̀ láéláé, baba wa, àti bí ó ti sọ fún àwọn baba wa.”
56
Maria sì jókòó tì Elisabeti níwọ̀n oṣù mẹ́ta, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options