Skip to content
Luku 1:46-55

Luku 1:46-55

46
Maria sì dáhùn, ó ní: “Ọkàn mi yin Olúwa lógo.
47
Ẹ̀mí mi sì yọ̀ sí Ọlọ́run Olùgbàlà mi.
48
Nítorí tí ó síjú wo ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ọmọbìnrin ọ̀dọ̀ rẹ̀. Sá wò ó, láti ìsinsin yìí lọ gbogbo ìran ènìyàn ni yóò máa pè mí ní alábùkún fún.
49
Nítorí ẹni tí ó ní agbára ti ṣe ohun tí ó tóbi fún mi; Mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀.
50
Àánú rẹ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, láti ìrandíran.
51
Ó ti fi agbára hàn ní apá rẹ̀; o ti tú àwọn onígbèéraga ká ní ìrònú ọkàn wọn.
52
Ó ti mú àwọn alágbára kúrò lórí ìtẹ́ wọn, o sì gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ lékè.
53
Ó ti fi ohun tí ó dára kún àwọn tí ebi ń pa ó sì rán àwọn ọlọ́rọ̀ padà ní òfo.
54
Ó ti ran Israẹli ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́, ní ìrántí àánú rẹ̀;
55
sí Abrahamu àti àwọn ìran rẹ̀ láéláé, baba wa, àti bí ó ti sọ fún àwọn baba wa.”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options