Ẹkún Jeremiah 3:32-56
32
Lóòtítọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn, nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀.
33
Nítorí kò mọ̀ ọ́n mọ̀ mú ìpọ́njú wá tàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn.
34
Láti tẹ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ilẹ̀ náà.
35
Láti ṣẹ́ ọmọ ènìyàn fún ẹ̀tọ́ rẹ̀ níwájú Ọ̀gá-ògo jùlọ,
36
láti yí ìdájọ́ ènìyàn padà, ǹjẹ́ Olúwa kò rí ohun bẹ́ẹ̀.
37
Ta ni yóò sọ̀rọ̀ tí yóò rí bẹ́ẹ̀ tí Olúwa kò bá fi àṣẹ sí i.
38
Ǹjẹ́ kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá-ògo jùlọ ni rere àti búburú tí ń wá?
39
Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè ṣe ń kùn nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?
40
Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀nà wa, kí a sì dán an wò, kí a sì tọ Olúwa lọ.
41
Ẹ jẹ́ kí a gbé ọkàn àti ọwọ́ wa sókè sí Ọlọ́run ní ọ̀run, kí a wí pé,
42
“Àwa ti ṣẹ̀ a sì ti ṣọ̀tẹ̀ ìwọ kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.
43
“Ìwọ fi ìbínú bo ara rẹ ìwọ sì ń lépa wa; ìwọ ń parun láìsí àánú.
44
Ìwọ ti fi àwọsánmọ̀ bo ara rẹ pé kí àdúrà wa má ba à dé ọ̀dọ̀ rẹ.
45
Ó ti sọ wá di èérí àti ààtàn láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.
46
“Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọn gbòòrò sí wa.
47
Àwa ti jìyà àti ìparun, nínú ìbẹ̀rù àti ewu.”
48
Omijé ń sàn ní ojú mi bí odò nítorí a pa àwọn ènìyàn mi run.
49
Ojú mi kò dá fún omijé, láì sinmi,
50
títí ìgbà tí Olúwa yóò síjú wolẹ̀ láti òkè ọ̀run tí yóò sì rí i.
51
Ohun tí mo rí mú ìbẹ̀rù wá ọkàn mi nítorí gbogbo àwọn obìnrin ìlú mi.
52
Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí dẹ mí bí ẹyẹ.
53
Wọ́n gbìyànjú láti mú òpin dé bá ayé mi nínú ihò wọ́n sì ju òkúta lù mí.
54
Orí mi kún fún omi, mo sì rò pé ìgbẹ̀yìn dé.
55
Mo pe orúkọ rẹ, Olúwa, láti ọ̀gbun ìsàlẹ̀ ihò.
56
Ìwọ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, “Má ṣe di etí rẹ sí igbe ẹ̀bẹ̀ mi fún ìtura.”
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings