Johanu 9:30-41
30
Ọkùnrin náà dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ohun ìyanu sá à ni èyí, pé ẹ̀yin kò mọ ibi tí ó tí wá, ṣùgbọ́n òun sá à ti là mí lójú.
31
Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run kì í gbọ́ ti ẹlẹ́ṣẹ̀; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣe olùfọkànsìn sí Ọlọ́run, tí ó bá sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, Òun ni ó ń gbọ́ tirẹ̀.
32
Láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, a kò ì tí ì gbọ́ pé ẹnìkan la ojú ẹni tí a bí ní afọ́jú rí.
33
Ìbá ṣe pé ọkùnrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, kì bá tí lè ṣe ohunkóhun.”
34
Sí èyí, wọ́n fèsì pé, “Láti ìbí ni o tì jíngírí nínú ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ ha fẹ́ kọ́ wa bí?” Wọ́n sì tì í sóde.
35
Jesu gbọ́ pé, wọ́n ti tì í sóde; nígbà tí ó sì rí i, ó wí pe, “Ìwọ gba Ọmọ Ọlọ́run, gbọ́ bí?”
36
Òun sì dáhùn wí pé, “Ta ni, Olúwa, kí èmi lè gbà á gbọ́?”
37
Jesu wí fún un pé, “Ìwọ ti rí i, Òun náà sì ni ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí.”
38
Ó sì wí pé, “Olúwa, mo gbàgbọ́,” ó sì wólẹ̀ fún un.
39
Jesu sì wí pé, “Nítorí ìdájọ́ ni mo ṣe wá sí ayé yìí, kí àwọn tí kò ríran lè ríran; àti kí àwọn tí ó ríran lè di afọ́jú.”
40
Nínú àwọn Farisi tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa pẹ̀lú fọ́jú bí?”
41
Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá ṣe pé ẹ̀yin fọ́jú, ẹ̀yin kì bá tí lẹ́sẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa ríran,’ nítorí náà ẹ̀ṣẹ̀ yín wà síbẹ̀.
Settings