Ọkùnrin náà gbèjà Jésù, wọ́n sì lé e jáde
24
Nítorí náà, wọ́n pe ọkùnrin afọ́jú náà lẹ́ẹ̀kejì, wọ́n sì wí fún un pé, “Fi ògo fún Ọlọ́run, àwa mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọkùnrin yìí jẹ́.”
25
Nítorí náà, ó dáhùn ó sì wí pé, “Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni, èmi kò mọ̀, Ohun kan ni mo mọ̀, pé mo tí fọ́jú rí, nísinsin yìí mo ríran.”
26
Nítorí náà, wọ́n wí fún un pé, “Kí ni ó ṣe ọ́? Báwo ni ó ṣe là ọ́ lójú.”
27
Ó dá wọn lóhùn wí pé, “Èmi ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, ẹ̀yin kò sì gbọ́, nítorí kín ni ẹ̀yin ṣe ń fẹ́ tún gbọ́? Ẹ̀yin pẹ̀lú ń fẹ́ ṣe ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bí?”
28
Wọ́n sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì wí pé, “Ìwọ ni ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ṣùgbọ́n ọmọ-ẹ̀yìn Mose ni àwa.
29
Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run bá Mose sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti eléyìí, àwa kò mọ ibi tí ó ti wá.”
30
Ọkùnrin náà dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ohun ìyanu sá à ni èyí, pé ẹ̀yin kò mọ ibi tí ó tí wá, ṣùgbọ́n òun sá à ti là mí lójú.
31
Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run kì í gbọ́ ti ẹlẹ́ṣẹ̀; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣe olùfọkànsìn sí Ọlọ́run, tí ó bá sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, Òun ni ó ń gbọ́ tirẹ̀.
32
Láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, a kò ì tí ì gbọ́ pé ẹnìkan la ojú ẹni tí a bí ní afọ́jú rí.
33
Ìbá ṣe pé ọkùnrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, kì bá tí lè ṣe ohunkóhun.”
34
Sí èyí, wọ́n fèsì pé, “Láti ìbí ni o tì jíngírí nínú ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ ha fẹ́ kọ́ wa bí?” Wọ́n sì tì í sóde.
Settings