- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Jésù gbọ́dọ̀ gba Sámáríà kọjá
Johanu 4:4-6
Jésù gbọ́dọ̀ gba Sámáríà kọjá
4
Òun sì ní láti kọjá láàrín Samaria.
5
Nígbà náà ni ó dé ìlú Samaria kan, tí a ń pè ní Sikari, tí ó súnmọ́ etí ilẹ̀ oko tí Jakọbu ti fi fún Josẹfu, ọmọ rẹ̀.
6
Kànga Jakọbu sì wà níbẹ̀. Nítorí pé ó rẹ Jesu nítorí ìrìn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó jókòó létí kànga, ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́.
Kẹ́kọ̀ọ́ ẹsẹ wọ̀nyí
Àlàyé lórí gbogbo ẹsẹ wọ̀nyí, kì í ṣe ẹsẹ kan ṣoṣo
- Ta ni
- Níbo
- Ìgbà wo
- About
Ibi mìíràn tí Ìwé Mímọ́ ti sọ èyí
Joṣua 24:32
Egungun Josẹfu, èyí tí àwọn ọmọ Israẹli kó kúrò ní Ejibiti, ni wọ́n sin ní Ṣekemu ní ìpín ilẹ̀ tí Jakọbu rà fún ọgọ́rùn-ún fàdákà ní ọwọ́ Hamori, baba Ṣekemu. Èyí sì jẹ́ ilẹ̀ ìní àwọn ọmọ Josẹfu.láti ẹsẹ 5Gẹnẹsisi 33:19
Ó sì ra ilẹ̀ kan tí ó pàgọ́ sí ni ọgọ́rùn-ún owó fàdákà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori tí í ṣe baba Ṣekemu.láti ẹsẹ 5Gẹnẹsisi 48:22
Pẹ̀lúpẹ̀lú èmi yóò fún ọ ní ìpín kan ju ti àwọn arákùnrin rẹ lọ. Ilẹ̀ tí mo fi idà àti ọ̀kọ̀ mi gbà lọ́wọ́ àwọn ará Amori.”láti ẹsẹ 5Luku 17:11
Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ sí Jerusalẹmu, ó kọjá láàrín Samaria Galili.láti ẹsẹ 4Heberu 4:15
Nítorí a kò ní olórí àlùfáà tí kò lè ṣàì ba ni kẹ́dùn nínú àìlera wa, ẹni tí a ti dánwò lọ́nà gbogbo gẹ́gẹ́ bí àwa, ṣùgbọ́n òun kò dẹ́ṣẹ̀.láti ẹsẹ 6Heberu 2:17
Nítorí náà, ó yẹ pé nínú ohun gbogbo kí ó dàbí àwọn ará rẹ̀, kí ó lè jẹ́ aláàánú àti olóòtítọ́ alábojútó Àlùfáà nínú ohun tí i ṣe ti Ọlọ́run, kí o lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn.láti ẹsẹ 6Matiu 8:24
Ní àìròtẹ́lẹ̀, ìjì líle dìde lórí Òkun tó bẹ́ẹ̀ tí rírú omi fi bò ọkọ̀ náà mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n Jesu ń sùn.láti ẹsẹ 6Luku 9:51
Nígbà tí ọjọ́ àti gbà á sókè ń súnmọ́, ó pinnu láti lọ sí Jerusalẹmu.láti ẹsẹ 4Luku 9:52
Ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ lọ sí iwájú rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì lọ wọ́n wọ ìletò kan tí í ṣe ti ará Samaria láti pèsè sílẹ̀ dè é.láti ẹsẹ 4Johanu 4:12
Ìwọ pọ̀ ju Jakọbu baba wa lọ bí, ẹni tí ó fún wa ní kànga náà, tí òun tìkára rẹ̀ si mu nínú rẹ̀, àti àwọn ọmọ rẹ̀, àti àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀?”láti ẹsẹ 5Luku 2:49
Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá mi kiri? Ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi kò lè ṣàìmá wà níbi iṣẹ́ Baba mi?”láti ẹsẹ 4Matiu 4:2
Lẹ́yìn tí Òun ti gbààwẹ̀ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ebi sì ń pa á.láti ẹsẹ 6



Àkọsílẹ̀ Ẹ̀kọ́
Settings