Jobu 31:21-40
21
bí mo bá sì gbé ọwọ́ mi sókè sí aláìní baba, nítorí pé mo rí ìrànlọ́wọ́ mi ní ẹnu ibodè,
22
ǹjẹ́, ní apá mi kí o wọ́n kúrò ní ihò èjìká rẹ̀, kí apá mi kí ó sì ṣẹ́ láti egungun rẹ̀ wá.
23
Nítorí pé ìparun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ẹ̀rù ńlá fún mi, àti nítorí ọláńlá rẹ̀ èmi kò le è dúró.
24
“Bí ó bá ṣe pé mo fi wúrà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé mi, tàbí tí mo bá wí fún fàdákà dídára pé, ‘Ìwọ ni ààbò mi,’
25
bí mo bá yọ̀ nítorí ọrọ̀ mí pọ̀, àti nítorí ọwọ́ mi dara lọ́pọ̀lọ́pọ̀,
26
bí mo bá bojú wo oòrùn nígbà tí ń ràn, tàbí òṣùpá tí ń ràn nínú ìtànmọ́lẹ̀,
27
bí a bá tàn ọkàn mi jẹ láti fi ẹnu mi kò ọwọ́ mi,
28
èyí pẹ̀lú ni ẹ̀ṣẹ̀ ti àwọn onídàájọ́ ní láti bẹ̀wò, nítorí pé èmí yóò jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run tí ó wà lókè.
29
“Bí ó bá ṣe pé mo yọ̀ sì ìparun ẹni tí ó kórìíra mi. Tàbí bí mo bá sì gbéraga sókè, nígbà tí ibi bá a.
30
Bẹ́ẹ̀ èmi kò sì jẹ ki ẹnu mi ki ó ṣẹ̀ nípa fífẹ́ ègún sí ọkàn rẹ̀.
31
Bí àwọn ènìyàn inú àgọ́ mi kò bá lè wí pé, ‘Ta ni kò ì tí ì jẹ ẹran rẹ̀ ní àjẹyó?’
32
Àlejò kò wọ̀ ni ìgboro rí; èmí ṣí ìlẹ̀kùn mi sílẹ̀ fún èrò.
33
Bí mo bá bò ẹ̀ṣẹ̀ mi mọ́lẹ̀ bí Adamu ni pápá, ẹ̀bi mi pamọ́ ni àyà mi.
34
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni mo ha bẹ̀rù bí? Tàbí ẹ̀gàn àwọn ìdílé ní ń bà mí ní ẹ̀rù? Tí mo fi pa ẹnu mọ́, tí èmí kò sì fi sọ̀rọ̀ jáde?
35
(“Ìbá ṣe pé ẹnìkan le gbọ́ ti èmí! Kíyèsi i, àmì mi, kí Olódùmarè kí ó dá mi lóhùn, kí èmí kí ó sì rí ìwé náà tí olùfisùn mi ti kọ.
36
Nítòótọ́ èmí ìbá gbé le èjìká mi, èmi ìbá sì dé bí adé mọ́ orí mi.
37
Èmi ìbá sì sọ iye ìṣísẹ̀ mi fún un, bí ọmọ-aládé ni èmi ìbá súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.)
38
“Bí ilẹ̀ mi bá sì ké rara lòdì sí mi tí a sì fi omijé kún gbogbo poro rẹ̀.
39
Bí mo bá jẹ èso oko mi láìsan owó tàbí tí mo sì mú ọkàn olúwa rẹ̀ fò lọ,
40
kí ẹ̀gún òṣùṣú kí ó hù dípò alikama, àti èpò búburú dípò ọkà barle.” Ọ̀rọ̀ Jobu parí.
Settings