Skip to content
Isaiah 8:4-10

Isaiah 8:4-10

4
Kí ọmọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń sọ pé, ‘Baba mi’ tàbí ‘Ìyá mi,’ gbogbo ọrọ̀ Damasku àti ìkógun ti Samaria ni ọba àwọn Asiria yóò ti kó lọ.”
5
Olúwa sì tún sọ fún mi pé,
6
“Nítorí pé àwọn ènìyàn yìí ti kọ omi Ṣiloa tí ń sàn jẹ́ẹ́jẹ́ sílẹ̀ tí wọ́n sì ń yọ̀ nínú Resini àti ọmọ Remaliah,
7
ǹjẹ́ nítorí náà kíyèsi i, Olúwa ń fa omi odò tí ó le, tí ó sì pọ̀ wá sórí wọn, àní, ọba Asiria àti gbogbo ògo rẹ̀, yóò sì wá sórí gbogbo ọ̀nà odò rẹ̀, yóò sì gun orí gbogbo bèbè rẹ̀,
8
yóò sì gbá àárín Juda kọjá, yóò sì ṣàn bò ó mọ́lẹ̀, yóò sì mú un dọ́rùn. Nínà ìyẹ́ apá rẹ̀ yóò sì bo gbogbo ìbú ilẹ̀ rẹ̀, ìwọ Emmanueli.”
9
Ké ariwo ogun, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, kí a sì fọ́ ọ yín túútúú, fetísílẹ̀, ẹ̀yin ilẹ̀ jíjìn réré. Ẹ palẹ̀mọ́ fún ogun, kí a sì fọ́ ọ túútúú!
10
Ẹ gbìmọ̀ pọ̀, yóò sì di asán, ẹ gbèrò ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n kì yóò dúró, nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa.
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options