Skip to content
Isaiah 49:1-13

Isaiah 49:1-13

1
Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin erékùṣù: gbọ́ èyí, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè jíjìnnà réré: kí a tó bí mi Olúwa ti pè mí; láti ìgbà bíbí mi ni ó ti dá orúkọ mi.
2
Ó ṣe ẹnu mi bí idà tí a pọ́n, ní abẹ́ òjìji ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti pa mí mọ́: ó ṣe mí ní ọfà tí a ti dán, ó sì fi mí pamọ́ sínú àpò rẹ̀.
3
Ó sọ fún mi pé, “Ìránṣẹ́ mi ni ìwọ í ṣe, Israẹli nínú ẹni tí n ó ti fi ògo mi hàn.”
4
Ṣùgbọ́n èmi sọ pé, “Mo ti ṣe wàhálà lórí asán; mo ti lo gbogbo ipá mi lórí asán àti ìmúlẹ̀mófo. Síbẹ̀síbẹ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi ṣì wà lọ́wọ́ Olúwa, èrè mi sì ń bẹ pẹ̀lú Ọlọ́run mi.”
5
Nísinsin yìí Olúwa wí pé ẹni tí ó mọ̀ mí láti inú wá láti jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ láti mú Jakọbu padà tọ̀ mí wá àti láti kó Israẹli jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, nítorí pé a bọ̀wọ̀ fún mi ní ojú Olúwa Ọlọ́run mi sì ti jẹ́ agbára mi,
6
Òun wí pé: “Ó jẹ́ ohun kékeré fún ọ láti jẹ́ ìránṣẹ́ mi láti mú ẹ̀yà Jakọbu padà bọ̀ sípò àti láti mú àwọn ti Israẹli tí mo ti pamọ́. Èmi yóò sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn kèfèrí, kí ìwọ kí ó lè mú ìgbàlà mi wá sí òpin ilẹ̀ ayé.”
7
Ohun tí Olúwa wí nìyìí, Olùdáǹdè àti Ẹni Mímọ́ Israẹli— sí ẹni náà tí a gàn tí a sì kórìíra lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, sí ìránṣẹ́ àwọn aláṣẹ: “Àwọn ọba yóò rí ọ wọn yóò sì dìde sókè, àwọn ọmọ ọba yóò rí i wọn yóò sì wólẹ̀, nítorí Olúwa ẹni tí í ṣe olóòtítọ́, Ẹni Mímọ́ Israẹli tí ó ti yàn ọ́.”
8
Ohun tí Olúwa wí nìyìí: “Ní àkókò ojúrere mi, èmi yóò dá ọ lóhùn, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́; Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́ láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn, láti mú ilẹ̀ padà bọ̀ sípò àti láti ṣe àtúnpín ogún rẹ̀ tí ó ti dahoro,
9
láti sọ fún àwọn ìgbèkùn pé, ‘Ẹ jáde wá,’ àti fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn pé, ‘Ẹ gba òmìnira!’ “Wọn yóò máa jẹ ní ẹ̀bá ọ̀nà àti koríko tútù lórí òkè aláìléwéko.
10
Ebi kì yóò pa wọ́n bẹ́ẹ̀ ni òǹgbẹ kì yóò gbẹ wọ́n, tàbí kí ooru inú aṣálẹ̀ tàbí oòrùn kí ó pa wọ́n. Ẹni tí ó ṣàánú fún wọn ni yóò máa tọ́ wọn, tí yóò sì mú wọn lọ sí ibi orísun omi.
11
Èmi yóò sọ gbogbo àwọn òkè ńlá mi di ojú ọ̀nà àti gbogbo òpópónà mi ni a ó gbé sókè.
12
Kíyèsi i, wọn yóò wá láti ọ̀nà jíjìn àwọn díẹ̀ láti àríwá àti àwọn díẹ̀ láti ìwọ̀-oòrùn, àwọn díẹ̀ láti ẹkùn Siene.”
13
Ẹ hó fún ayọ̀, ẹyin ọ̀run; yọ̀, ìwọ ilẹ̀ ayé; bú sórin, ẹ̀yin òkè ńlá! Nítorí Olúwa tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú yóò sì ṣàánú fún àwọn ẹni tí a ń pọ́n lójú.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options