Isaiah 37:21-29
21
Lẹ́yìn náà Isaiah ọmọ Amosi rán iṣẹ́ kan sí Hesekiah: “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli sọ pé, nítorí pé ìwọ ti gbàdúrà sí mi nípa Sennakeribu ọba Asiria,
22
èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀: “Wúńdíá ọmọbìnrin Sioni ti kẹ́gàn rẹ, ó sì ti fi ọ ṣe ẹlẹ́yà. Ọmọbìnrin Jerusalẹmu ti mi orí rẹ̀ bí ó ti ń sálọ.
23
Ta ni ìwọ ti bú tí ìwọ sì ti sọ̀rọ̀-òdì sí? Sí ta ní ìwọ ti gbé ohùn rẹ sókè tí o sì gbé ojú rẹ sókè ní ìgbéraga? Sí Ẹni Mímọ́ Israẹli!
24
Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ, ìwọ ti sọ̀rọ̀ búburú sí Olúwa. Tì wọ sì wí pé, ‘Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ mi ni èmi sì fi dé orí àwọn òkè ńlá, sí ibi gíga jùlọ Lebanoni. Èmi a sì ké igi kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀, àti ààyò igi firi rẹ̀. Èmi ti dé ibi rẹ̀ tí ó ga jùlọ, igbó rẹ̀ tí ó dára jùlọ.
25
Èmi ti gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjì mo sì mu omi ní ibẹ̀, pẹ̀lú àtẹ́lẹsẹ̀ mi Èmi ti gbẹ́ gbogbo omi àwọn odò Ejibiti.’
26
“Ṣé o kò tí ì gbọ́? Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti fìdí rẹ̀ mulẹ̀. Láti ìgbà pípẹ́ ni mo ti ṣètò rẹ̀; ní àkókò yìí ni mo mú wá sí ìmúṣẹ, pé o ti sọ àwọn ìlú olódi di àkójọpọ̀ àwọn òkúta.
27
Àwọn ènìyàn, tí agbára ti wọ̀ lẹ́wù, ni wọ́n banújẹ́ tí a sì dójútì. Wọ́n dàbí ohun ọ̀gbìn nínú pápá, gẹ́gẹ́ bí ọ̀jẹ̀lẹ̀ èhíhù tuntun, gẹ́gẹ́ bí i koríko tí ó ń hù lórí òrùlé, tí ó jóná kí ó tó dàgbàsókè.
28
“Ṣùgbọ́n mo mọ ibi tí o wà àti ìgbà tí o wá tí o sì lọ àti bí inú rẹ ṣe ru sí mi.
29
Nítorí pé inú rẹ ru sí mi àti nítorí pé orí kunkun rẹ ti dé etí ìgbọ́ mi, Èmi yóò fi ìwọ̀ mi sí ọ ní imú, àti ìjẹ mi sí ọ lẹ́nu, èmi yóò sì jẹ́ kí o padà láti ọ̀nà tí o gbà wá.
Settings