Skip to content
Isaiah 33:1-9

Isaiah 33:1-9

1
Ègbé ni fún ọ, ìwọ apanirun, ìwọ tí a kò tí ì parun! Ègbé ni fún ọ, ìwọ ọ̀dàlẹ̀, ìwọ tí a kò tí ì dà ọ́! Nígbà tí o bá dẹ́kun à ń pa ni run; a ó pa ìwọ náà run, nígbà tí o bá dẹ́kun à ń dani, a ó da ìwọ náà.
2
Olúwa ṣàánú fún wa àwa ń ṣàfẹ́rí i rẹ. Máa jẹ́ agbára wa ní òròòwúrọ̀ ìgbàlà wa ní àsìkò ìpọ́njú.
3
Ní ìkérara ohùn rẹ, àwọn ènìyàn sá, nígbà tí o dìde sókè, àwọn orílẹ̀-èdè fọ́nká.
4
Ìkógun rẹ, ìwọ orílẹ̀-èdè ni a kórè gẹ́gẹ́ bí i ti ọ̀dọ́ eṣú; gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ eṣú, àwọn ènìyàn wọ ibẹ̀.
5
A gbé Olúwa ga, nítorí pé ó ń gbé ibi gíga, Òun yóò kún Sioni pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àti òdodo.
6
Òun yóò jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún àkókò rẹ ibùjókòó ìgbàlà kíkún àti ọgbọ́n òun ìmọ̀; ìbẹ̀rù Olúwa ni kọ́kọ́rọ́ sí ìṣúra yìí.
7
Wò ó, àwọn onígboyà ọkùnrin wọn pohùnréré ẹkún ní òpópónà; àwọn ikọ̀ àlàáfíà sọkún kíkorò.
8
Àwọn ojú ọ̀nà ńlá ni a ṣá tì, kò sí arìnrìn-àjò kankan ní ojú ọ̀nà. A ti ba àdéhùn jẹ́, a kẹ́gàn àwọn ẹlẹ́rìí, a kò bu ọlá fún ẹnikẹ́ni.
9
Ilẹ̀ ṣọ̀fọ̀ ó sì ṣòfò dànù, ojú ti Lebanoni ó sì sá Ṣaroni sì dàbí aginjù, àti Baṣani òun Karmeli rẹ àwọn èwe wọn.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options