Isaiah 33:7-12
7
Wò ó, àwọn onígboyà ọkùnrin wọn pohùnréré ẹkún ní òpópónà; àwọn ikọ̀ àlàáfíà sọkún kíkorò.
8
Àwọn ojú ọ̀nà ńlá ni a ṣá tì, kò sí arìnrìn-àjò kankan ní ojú ọ̀nà. A ti ba àdéhùn jẹ́, a kẹ́gàn àwọn ẹlẹ́rìí, a kò bu ọlá fún ẹnikẹ́ni.
9
Ilẹ̀ ṣọ̀fọ̀ ó sì ṣòfò dànù, ojú ti Lebanoni ó sì sá Ṣaroni sì dàbí aginjù, àti Baṣani òun Karmeli rẹ àwọn èwe wọn.
10
“Ní ìsinsin yìí ni èmi yóò dìde,” ni Olúwa wí. “Ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi ga, ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi sókè.
11
Ìwọ lóyún ìyàngbò, o sì bí koríko; èémí yín bí iná tí yóò jẹ yín run.
12
A ó jó àwọn ènìyàn run bí eérú; bí igbó ẹ̀gún tí a gé la ó dáná sí wọn.”
Settings