Gẹnẹsisi 26:1-6
1
Ìyàn kan sì mú ní ilẹ̀ náà, yàtọ̀ fún èyí tí ó mú ní ìgbà ayé Abrahamu, Isaaki sì lọ sọ́dọ̀ Abimeleki ọba àwọn Filistini ni Gerari.
2
Olúwa sì fi ara han Isaaki, ó sì wí pé, “Má ṣe sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti, jókòó ní ilẹ̀ tí èmi ó fún ọ.
3
Máa ṣe àtìpó ní ilẹ̀ yìí fún ìgbà díẹ̀, èmi ó sì wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì bùkún fún ọ. Nítorí ìwọ àti irú-ọmọ rẹ ni èmi yóò fi gbogbo àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí fún, èmi yóò sì fi ìdí ìbúra tí mo ṣe fún Abrahamu baba rẹ múlẹ̀.
4
Èmi yóò sọ ìran rẹ di púpọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, èmi yóò sì fi gbogbo ilẹ̀ yìí fún irú àwọn ọmọ rẹ, àti nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni a ó bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé,
5
nítorí tí Abrahamu gba ohùn mi gbọ́, ó sì pa gbogbo ìkìlọ̀, àṣẹ, ìlànà àti òfin mi mọ́.”
6
Nítorí náà Isaaki jókòó ní Gerari.
Settings