Gẹnẹsisi 10:3
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 3 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
1
Èyí ni ìran àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti, tí àwọn náà sì bí ọmọ lẹ́yìn ìkún omi.
2
Àwọn ọmọ Jafeti ni: Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi.
3
Àwọn ọmọ Gomeri ni: Aṣkenasi, Rifati àti Togarma.
4
Àwọn ọmọ Jafani ni: Eliṣa, Tarṣiṣi, Kittimu, àti Dodanimu.
5
(Láti ọ̀dọ̀ àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ń gbé agbègbè tí omi wà ti tàn ká agbègbè wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, ìdílé wọn ní orílẹ̀-èdè wọn, olúkúlùkù pẹ̀lú èdè tirẹ̀).
6
Àwọn ọmọ Hamu ni: Kuṣi, Ejibiti, Puti àti Kenaani.
Settings