Skip to content
Esra 6:6

Esra 6:6

Ń ṣàfihàn ẹsẹ 6 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
3
Ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba ọba Kirusi, ọba pa àṣẹ kan nípa tẹmpili Ọlọ́run ní Jerusalẹmu. Jẹ́ kí a tún tẹmpili ibi tí a ti ń rú onírúurú ẹbọ kọ́, kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ ni gíga àti fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ àádọ́rùn-ún ẹsẹ̀ bàtà,
4
pẹ̀lú ipele òkúta ńlá ńlá mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ipele pákó kan, kí a san owó rẹ̀ láti inú ilé ìṣúra ọba.
5
Sì jẹ́ kí wúrà àti àwọn ohun èlò fàdákà ti ilé Ọlọ́run, tí Nebukadnessari kó láti ilé Olúwa ní Jerusalẹmu tí ó sì kó lọ sí Babeli, di dídápadà sí ààyè wọn nínú tẹmpili ní Jerusalẹmu; kí a kó wọn sí inú ilé Ọlọ́run.
6
Nítorí náà, kí ìwọ, Tatenai baálẹ̀ agbègbè Eufurate àti Ṣetar-bosnai àti àwọn ẹlẹgbẹ́ yín, àwọn ìjòyè ti agbègbè náà kúrò níbẹ̀.
7
Ẹ fi iṣẹ́ ilé Ọlọ́run yìí lọ́rùn sílẹ̀ láì dí i lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí baálẹ̀ àwọn Júù àti àwọn àgbàgbà Júù tún ilé Ọlọ́run yín kọ́ sí ipò rẹ̀.
8
Síwájú sí i, mo pàṣẹ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe fún àwọn àgbàgbà Júù wọ̀nyí lórí kíkọ́ ilé Ọlọ́run yìí. Gbogbo ìnáwó àwọn ọkùnrin yìí ni kí ẹ san lẹ́kùnrẹ́rẹ́ lára ìṣúra ti ọba, láti ibi àkójọpọ̀ owó ìlú ti agbègbè Eufurate kí iṣẹ́ náà má bà dúró.
9
Ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́—àwọn ọ̀dọ́ akọ màlúù, àwọn àgbò, ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun sí Ọlọ́run ọ̀run, àti jéró, iyọ̀, wáìnì àti òróró, bí àwọn àlùfáà ní Jerusalẹmu ti béèrè ni ẹ gbọdọ̀ fún wọn lójoojúmọ́ láìyẹ̀.
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 90 chars

Options