Skip to content
Esra 4:17-24

Esra 4:17-24

17
Ọba fi èsì yìí ránṣẹ́ padà. Sí Rehumu balógun, Ṣimṣai akọ̀wé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù tí ń gbé ní Samaria àti ní òpópónà Eufurate. Ìkíni.
18
A ti ka ìwé tí ẹ fi ránṣẹ́ sí wa, a sì ti túmọ̀ rẹ̀ níwájú mi.
19
Mo pa àṣẹ, a sì ṣe ìwádìí, nínú ìtàn ọjọ́ pípẹ́ àti ti ìsinsin yìí ti ìṣọ̀tẹ̀ sí àwọn ọba pẹ̀lú, ó sì jẹ́ ibi ìṣọ̀tẹ̀ àti ìrúkèrúdò.
20
Jerusalẹmu ti ní àwọn ọba alágbára tí ń jẹ ọba lórí gbogbo àwọn agbègbè Eufurate, àti àwọn owó orí, owó òde àti owó ibodè sì ni wọ́n ń san fún wọn.
21
Nísinsin yìí pa àṣẹ fún àwọn ọkùnrin yìí láti dá iṣẹ́ dúró, kí a má ṣe tún ìlú náà kọ títí èmi yóò fi pàṣẹ.
22
Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe àìkọbi-ara sí ọ̀rọ̀ yìí. Èéṣe tí ìbàjẹ́ yóò fi pọ̀ sí i, sí ìpalára àwọn ọba?
23
Ní kété tí a ka ẹ̀dà ìwé ọba Artasasta sí Rehumu àti Ṣimṣai akọ̀wé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, wọ́n yára lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn Júù ní Jerusalẹmu pẹ̀lú, wọ́n fi agbára mú wọn láti dáwọ́ dúró.
24
Báyìí, iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu wá sí ìdúró jẹ́ẹ́ títí di ọdún kejì ìjọba Dariusi ọba Persia.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options