Skip to content
Eksodu 9:18-26

Eksodu 9:18-26

18
Nítorí náà, ni ìwòyí ọ̀la, Èmi yóò rán òjò o yìnyín tí irú rẹ̀ kò tí i rọ̀ rí ni Ejibiti láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ títí di àkókò yìí.
19
Pàṣẹ nísinsin yìí láti kó ẹran ọ̀sìn yín àti ohun gbogbo ti ẹ ni ní pápá wá sí abẹ́ ààbò, nítorí òjò yìnyín yóò rọ̀ sí orí àwọn ènìyàn àti ẹran ti a kò kó wá sí abẹ́ ààbò tí wọ́n sì wà ni orí pápá, wọn yóò sì kú.’ ”
20
Àwọn ti ó bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Olúwa lára àwọn ìjòyè Farao yára lọ láti kó àwọn ẹrú àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn wá sí abẹ́ ààbò.
21
Ṣùgbọ́n àwọn ti kò kà ọ̀rọ̀ Olúwa sí fi àwọn ẹrú wọn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sílẹ̀ ni pápá.
22
Olúwa sọ fún Mose pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ọ̀run kí yìnyín bá à lè rọ̀ sí orí gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, sí orí ènìyàn àti ẹranko, àti sí orí gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ni inú oko.”
23
Nígbà tí Mose gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè sí ojú ọ̀run, Olúwa rán àrá àti yìnyín, mọ̀nàmọ́ná sì bùsi orí ilẹ̀. Olúwa rọ òjò yìnyín sí orí ilẹ̀ Ejibiti.
24
Yìnyín rọ̀, mọ̀nàmọ́ná sì bẹ̀rẹ̀ sí bùsi orí ilẹ̀ èyí ni ó tí ì burú jù ti ó ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ti Ejibiti ti di orílẹ̀-èdè.
25
Jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti ni yìnyín ti pa gbogbo ohun tí ó wà ni orí pápá; ènìyàn àti ẹranko, ó wò gbogbo ohun ọ̀gbìn lulẹ̀ ó sì fa gbogbo igi ya pẹ̀lú.
26
Ilẹ̀ Goṣeni ni ibi ti àwọn Israẹli wà nìkan ni òjò yìnyín náà kò rọ̀ dé.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options