Skip to content
Eksodu 8:20-31

Eksodu 8:20-31

20
Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kí o sì ko Farao lójú bí ó ṣe ń lọ sí odò, kí o sì sọ fún un pé, ‘Èyí ni Olúwa sọ: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó bá à lè sìn Mi.
21
Bí ìwọ kò bá jẹ́ kí àwọn ènìyàn Mi kí ó lọ, èmi yóò rán ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣinṣin sí ara rẹ àti sí ara àwọn ìjòyè rẹ, àti sí ara àwọn ènìyàn rẹ̀, sí àwọn ilẹ̀ rẹ̀. Gbogbo ilé àwọn ará Ejibiti ni yóò kún fún eṣinṣin àti orí ilẹ̀ tí wọ́n wà pẹ̀lú.
22
“ ‘Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ náà, Èmi yóò ya ilẹ̀ Goṣeni sọ́tọ̀, níbi tí àwọn ènìyàn mi ń gbé, ọ̀wọ́ eṣinṣin kankan ki yóò dé ibẹ̀. Kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, mo wà ni ilẹ̀ yìí.
23
Èmi yóò pààlà sáàárín àwọn ènìyàn mi àti àwọn ènìyàn rẹ. Àwọn iṣẹ́ ìyanu yìí yóò ṣẹlẹ̀ ni ọ̀la.’ ”
24
Olúwa sì ṣe èyí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣinṣin sì ya wọ ààfin Farao àti sí ilé àwọn ìjòyè rẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ Ejibiti bàjẹ́ pẹ̀lú ọ̀wọ́ eṣinṣin wọ̀n-ọn-nì.
25
Nígbà náà ni Farao ránṣẹ́ pe Mose àti Aaroni, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ kí ẹ sì rú ẹbọ sí Ọlọ́run yín ní ilẹ̀ yìí.”
26
Ṣùgbọ́n Mose sọ pé, “Èyí ló tọ́, ẹbọ tí a ó rú sí Olúwa Ọlọ́run wa yóò jẹ́ ohun ìríra sí àwọn ará ilẹ̀ Ejibiti. Bí a bá ṣe ìrúbọ ti yóò jẹ́ ìríra ni ojú wọn ṣé wọn, ó ní sọ òkúta lù wá?
27
A gbọdọ̀ lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú aginjù láti rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún wa.”
28
Nígbà náà ni Farao wí pé, “Èmi yóò jẹ́ ki ẹ lọ rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run yín nínú aginjù, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ rìn jìnnà jù. Ẹ gbàdúrà fún mi.”
29
Mose dáhùn ó wí pé, “Bí èmi bá ti kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, èmi yóò gbàdúrà sí Olúwa, àwọn ọ̀wọ́ eṣinṣin yóò fi Farao, àwọn ìjòyè rẹ, àti àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀ ní ọ̀la ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ìdánilójú wa pé Farao kò tún ni lo ẹ̀tàn láti má jẹ́ kí àwọn ènìyàn kí ó lọ rú ẹbọ sí Olúwa.”
30
Nígbà náà ni Mose kúrò ni ọ̀dọ̀ Farao, ó sì gbàdúrà sí Olúwa;
31
Olúwa sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose ti béèrè. Àwọn ọ̀wọ́ eṣinṣin kúrò lára Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀ àti lára àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú, eṣinṣin kan kò sì ṣẹ́kù.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options