Eksodu 8:16-19
16
Olúwa sọ fún Mose pé, “Sọ fún Aaroni, ‘Na ọ̀pá rẹ jáde kí ó sì lu eruku ilẹ̀,’ jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti ni erùpẹ̀ ilẹ̀ yóò ti di kòkòrò-kantíkantí.” (Kòkòrò kan tí ó ní ìyẹ́ méjì tí ó ṣì ń ta ni.)
17
Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, nígbà tí Aaroni na ọwọ́ rẹ́ jáde pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó sì lu eruku ilẹ̀, kòkòrò-kantíkantí sì wà lára àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko wọn. Gbogbo eruku jákèjádò ilẹ̀ Ejibiti ni ó di kòkòrò-kantíkantí.
18
Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn onídán gbìdánwò láti da kòkòrò-kantíkantí pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn, wọn kò le è ṣé. Nígbà tí kòkòrò-kantíkantí sì wà lára àwọn ẹranko wọn,
19
àwọn onídán sì sọ fún Farao pé, “Ìka Ọlọ́run ni èyí.” Ṣùgbọ́n àyà Farao sì yigbì, kò sì fetísílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ.
Settings