Eksodu 36:20-25
20
Ó sì ṣe pákó igi kasia tí ó dúró òró fún àgọ́ náà.
21
Ọ̀kọ̀ọ̀kan pákó náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní fífẹ̀,
22
pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ méjì tí ó kọjú sí ara wọn. Wọ́n ṣe gbogbo pákó àgọ́ náà bí èyí.
23
Ó sì ṣe ogún pákó sí ìhà gúúsù àgọ́ náà.
24
Ó sì ṣe ogójì fàdákà ihò ìtẹ̀bọ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ wọn ìtẹ̀bọ̀ méjì fún pákó kọ̀ọ̀kan, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìsàlẹ̀ ìtẹ̀bọ̀.
25
Fún ìhà kejì, ìhà àríwá àgọ́ náà, wọ́n ṣe ogún pákó
Settings