Eksodu 33:1-6
1
Olúwa sọ fún Mose pé, “Fi ìhín yìí sílẹ̀, ìwọ àti àwọn ènìyàn tí o mú gòkè láti Ejibiti wá, kí ẹ sì gòkè lọ sí ilẹ̀ tí Èmi ti pinnu ní ìbúra fún Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu wí pé, ‘Èmi yóò fi fún irú-ọmọ rẹ.’
2
Èmi yóò rán angẹli ṣáájú yín, Èmi yóò sì lé àwọn Kenaani, àwọn ará Amori, àwọn ará Hiti, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi jáde.
3
Ẹ gòkè lọ sí ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin. Ṣùgbọ́n èmi kò ní lọ pẹ̀lú yín, nítorí ènìyàn ọlọ́rùn líle ni ẹ̀yin, kí èmi má ba à run yín ní ọ̀nà.”
4
Nígbà tí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ọ̀rọ̀ ìparun wọ̀nyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì ní kùn, ẹnìkankan kò sì le è wọ ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀.
5
Nítorí Olúwa ti wí fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ènìyàn Ọlọ́rùn líle ní ẹ̀yin, bí Èmi bá lè wá sí àárín yín ni ìṣẹ́jú kan, Èmi lè pa yín run. Nísìnsinyìí, bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ rẹ kúrò, Èmi yóò sì gbèrò ohun tí Èmi yóò ṣe pẹ̀lú rẹ.’ ”
6
Bẹ́ẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò lára wọn ní òkè Horebu.
Settings