Kolose 1:1-15
1
Paulu, aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Timotiu arákùnrin wa,
2
Sí àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú Kristi tí wọ́n ń gbé ní ìlú Kolose: Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún un yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa.
3
Nígbàkígbà tí a bá ń gbàdúrà fún un yín ni a máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Olúwa wa Jesu Kristi.
4
Nítorí a ti gbúròó ìgbàgbọ́ yín nínú Jesu Kristi, àti bí ẹ ti ṣe fẹ́ràn gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́.
5
Ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ń sàn nínú ìrètí tí a gbé pamọ́ fún un yín ní ọ̀run èyí tí ẹ̀yin sì ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́ ìyìnrere náà,
6
èyí tí ó ti dé ọ̀dọ̀ yín. Káàkiri àgbáyé ni ìyìnrere yìí ń so èso tí ó sì ń dàgbà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe láàrín yín láti ọjọ́ náà tí ẹ ti gbọ́ ọ, tí ẹ sì ní ìmọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nínú gbogbo òtítọ́ rẹ̀.
7
Ẹ̀yin ti kọ́ ọ lọ́dọ̀ Epafira, ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa olùfẹ́, ẹni tí ó jẹ́ olóòtítọ́ ìránṣẹ́ Kristi ní ipò wa.
8
Ẹni ti ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ yín nínú ẹ̀mí.
9
Nítorí ìdí èyí, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa yín, a kò sinmi láti máa gbàdúrà fún yin, tí a sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ìmọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ kún yín nípasẹ̀ ọgbọ́n àti òye gbogbo tí ń ṣe ti Ẹ̀mí.
10
Àwa sì ń gbàdúrà yìí kí ẹ lè gbé irú ìgbé ayé tó yẹ fún Olúwa kí ẹ sì máa wu ú ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ sì máa so èso rere gbogbo, kí ẹ sì máa dàgbà nínú ìmọ̀ Ọlọ́run,
11
pé kí a lè fi ipa gbogbo sọ yín di alágbára gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ àti ògo rẹ̀, kí ó lè ṣe é ṣe fún un yín láti máa tẹ̀síwájú nínú sùúrù àti ìpamọ́ra pẹ̀lú ayọ̀.
12
Kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo lọ́wọ́ Baba, ẹni tí ó kà yín láti jẹ́ alábápín nínú ogún àwọn ẹni mímọ́ nínú ìjọba ìmọ́lẹ̀.
13
Nítorí tí ó ti já wa gbà kúrò nínú agbára òkùnkùn ó sì mú wa wá sí ìjọba Ọmọ tí ó fẹ́ràn.
14
Nínú ẹni tí a ní ìràpadà, àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.
15
Kristi ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò le rí, àkọ́bí gbogbo ẹ̀dá.
Settings