2 Samuẹli 15:13-23
13
Ẹnìkan sì wá rò fún Dafidi pé, “Ọkàn àwọn ọkùnrin Israẹli ṣí sí Absalomu.”
14
Dafidi sì wí fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wá lọ́dọ̀ rẹ̀ ni Jerusalẹmu pé, “Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a sálọ, nítorí pé kò sí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ Absalomu; ẹ yára, kí a lọ kúrò, kí òun má bá à yára lé wa bá, kí ó má sì mú ibi bá wa, kí ó má sì fi ojú idà pa ìlú run.”
15
Àwọn ìránṣẹ́ ọba sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí olúwa wa ọba ń fẹ́, wò ó, àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ ti murá.”
16
Ọba sì jáde, gbogbo ilé rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Ọba sì fì mẹ́wàá nínú àwọn obìnrin rẹ̀ sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ilé.
17
Ọba sì jáde, gbogbo ènìyàn sì tẹ̀lé e, wọ́n sì dúró ní ibìkan tí ó jìnnà.
18
Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì kọjá sí iwájú rẹ̀, àti gbogbo àwọn Kereti, àti gbogbo àwọn Peleti, àti gbogbo àwọn ará Gitti, ẹgbẹ̀ta (600) ọmọkùnrin tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Gati wá, sì kọjá níwájú ọba.
19
Ọba sì wí fún Ittai ará Gitti pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń bá wa lọ pẹ̀lú, padà, kí o sì ba ọba jókòó; nítorí pé àlejò ni ìwọ, ìwọ sì ti fi ìlú rẹ sílẹ̀.
20
Lánàá yìí ni ìwọ dé, èmi ó ha sì mú kí ìwọ máa bá wá lọ káàkiri lónìí bí? Èmi ń lọ sí ibikíbi tí mo bá rí: padà, kí o sì mú àwọn arákùnrin rẹ padà, kí àánú àti òtítọ́ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”
21
Ittai sì dá ọba lóhùn, ó sì wí pé, “Bí Olúwa tí ń bẹ láààyè, àti bí olúwa mi ọba ti ń bẹ láààyè, nítòótọ́ níbikíbi tí olúwa mi ọba bá gbé wà, ìbá à ṣe nínú ikú, tàbí nínú ìyè, níbẹ̀ pẹ̀lú ni ìránṣẹ́ rẹ yóò gbé wà.”
22
Dafidi sì wí fún Ittai pé, “Lọ kí o sì rékọjá!” Ittai ará Gitti náà sì rékọjá, àti gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn ọmọ kéékèèké tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀.
23
Gbogbo ìlú náà sì fi ohùn rara sọkún, gbogbo ènìyàn sì rékọjá; ọba sì rékọjá àfonífojì Kidironi, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì rékọjá, sí ìhà ọ̀nà ijù.
Settings