2 Samuẹli 13:1-14
1
Ó sì ṣe, lẹ́yìn èyí, Absalomu ọmọ Dafidi ní àbúrò obìnrin kan tí ó ṣe arẹwà, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Tamari; Amnoni ọmọ Dafidi sì fẹ́ràn rẹ̀.
2
Amnoni sì banújẹ́ títí ó fi ṣe àìsàn nítorí Tamari àbúrò rẹ̀ obìnrin; nítorí pé wúńdíá ni; ó sì ṣe ohun tí ó ṣòro lójú Amnoni láti bá a dàpọ̀.
3
Ṣùgbọ́n Amnoni ní ọ̀rẹ́ kan, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Jonadabu, ọmọ Ṣimea ẹ̀gbọ́n Dafidi, Jonadabu sì jẹ́ alárékérekè ènìyàn gidigidi.
4
Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ ọmọ ọba ń fi ń rù lójoojúmọ́ báyìí? Ǹjẹ́ o kò ní sọ fún mi?” Amnoni sì wí fún un pé, “Èmi fẹ́ Tamari àbúrò Absalomu arákùnrin mi.”
5
Jonadabu sì wí fún un pé, “Dùbúlẹ̀ ní ibùsùn rẹ kí ìwọ sì díbọ́n pé, ìwọ kò sàn, baba rẹ yóò sì wá wò ọ́, ìwọ ó sì wí fún un pé, ‘Jọ̀wọ́ jẹ́ kí Tamari àbúrò mi wá kí ó sì fún mi ní oúnjẹ kí ó sì ṣe oúnjẹ náà níwájú mi kí èmi ó rí i, èmi ó sì jẹ ẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀.’ ”
6
Amnoni sì dùbúlẹ̀, ó sì díbọ́n pé òun ṣàìsàn, ọba sì wá wò ó, Amnoni sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Tamari àbúrò mi ó wá, kí ó sì dín àkàrà méjì lójú mi, èmi ó sì jẹ ní ọwọ́ rẹ̀.”
7
Dafidi sì ránṣẹ́ sí Tamari ní ilé pé, “Lọ sí ilé Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ, kí ó sì se oúnjẹ fún un.”
8
Tamari sì lọ sí ilé Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ̀, òun sì ń bẹ ní ìdùbúlẹ̀. Tamari sì mú ìyẹ̀fun, ó sì pò ó, ó sì fi ṣe àkàrà lójú rẹ̀, ó sì dín àkàrà náà.
9
Òun sì mú àwo náà, ó sì dà á sínú àwo mìíràn níwájú rẹ̀; ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti jẹ. Amnoni sì wí pé, “Jẹ́ kí gbogbo ọkùnrin jáde kúrò lọ́dọ̀ mi!” Wọ́n sì jáde olúkúlùkù ọkùnrin kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
10
Amnoni sì wí fún Tamari pé, “Mú oúnjẹ náà wá sí yàrá, èmi ó sì jẹ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ.” Tamari sì mú àkàrà tí ó ṣe, ó sì mú un tọ Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní yàrá.
11
Nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti fi oúnjẹ fún un, òun sì dìímú, ó sì wí fún un pé, “Wá dùbúlẹ̀ tì mí, àbúrò mi.”
12
Òun sì dá a lóhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀gbọ́n mi, má ṣe tẹ́ mi; nítorí pé kò tọ kí a ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ní Israẹli, ìwọ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí.
13
Àti èmi, níbo ni èmi ó gbé ìtìjú mi wọ̀? Ìwọ ó sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn aṣiwèrè ní Israẹli. Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́, sọ fún ọba; nítorí pé òun kì yóò kọ̀ láti fi mí fún ọ.”
14
Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti gbọ́ ohùn rẹ̀; ó sì fi agbára mú un, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀, ó sì bá a dàpọ̀.
Settings