Skip to content
2 Ọba 23:29-35

2 Ọba 23:29-35

29
Nígbà tí Josiah jẹ́ ọba, Farao Neko ọba Ejibiti gòkè lọ sí odò Eufurate láti lọ ran ọba Asiria lọ́wọ́. Ọba Josiah jáde lọ láti lọ bá a pàdé lójú ogun ṣùgbọ́n Neko dojúkọ ọ́, ó sì pa á ní Megido.
30
Ìránṣẹ́ Josiah gbé ara rẹ̀ wá nínú kẹ̀kẹ́ láti Megido sí Jerusalẹmu ó sì sin ín sínú isà òkú rẹ̀. Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú Jehoahasi ọmọ Josiah. Ó fi àmì òróró yàn án, ó sì ṣe é ní ọba ní ipò baba a rẹ̀.
31
Jehoahasi sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Hamutali ọmọbìnrin Jeremiah; ó wá láti Libina.
32
Ó ṣe búburú lójú Olúwa gẹ́gẹ́ bí baba a rẹ̀ ti ṣe.
33
Farao Neko sì fi sí inú ìdè ní Ribla ní ilẹ̀ Hamati, kí ó má ba à lè jẹ ọba ní Jerusalẹmu. Ó sì tan Juda jẹ fun iye ìwọ̀n ẹgbẹ̀rin tálẹ́ǹtì wúrà kan.
34
Farao Neko ṣe Eliakimu ọmọ Josiah ní ọba ní ipò baba rẹ̀ Josiah. Ó sì yí orúkọ Eliakimu padà sí Jehoiakimu. Ṣùgbọ́n ó mú Jehoahasi, ó sì gbé e lọ sí Ejibiti, níbẹ̀ ni ó sì kú.
35
Jehoiakimu sì san fún Farao Neko fàdákà àti wúrà tí ó béèrè. Láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó bu owó òde fún ilẹ̀ náà láti san, ó fi agbára gba fàdákà àti wúrà láti ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà ní ìbámu pẹ̀lú iye tí a pín.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options