1 Timotiu 2:9-15
9
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí àwọn obìnrin fi aṣọ ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ṣe ara wọn ní ọ̀ṣọ́, ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti pẹ̀lú ìwà àìrékọjá; kì í ṣe pẹ̀lú irun dídì, tàbí wúrà, tàbí peali, tàbí aṣọ olówó iyebíye,
10
bí kò ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ rere, èyí tí ó yẹ fún àwọn obìnrin tó jẹ́wọ́ pé wọ́n sin Ọlọ́run.
11
Jẹ́ kí obìnrin máa fi ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìtẹríba gbogbo kọ́ ẹ̀kọ́.
12
Ṣùgbọ́n èmi kò fi àṣẹ fún obìnrin láti máa kọ́ni, tàbí láti pàṣẹ lórí ọkùnrin, bí kò ṣe kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́.
13
Nítorí Adamu ni a kọ́ dá, lẹ́yìn náà, Efa.
14
Adamu kọ́ ni a tànjẹ, ṣùgbọ́n obìnrin náà ni a tàn tí ó sì di ẹlẹ́ṣẹ̀.
15
Ṣùgbọ́n a ó gbà àwọn obìnrin là nípa ìbímọ wọn, bí wọ́n bá dúró nínú ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àti ìwà mímọ́ pẹ̀lú ìwà àìrékọjá.
Settings