1 Timotiu 2:1-7
1
Nítorí náà mo gbà yín níyànjú ṣáájú ohun gbogbo, pé kí a máa bẹ̀bẹ̀, kí a máa gbàdúrà, kí a máa ṣìpẹ̀, àti kí a máa dúpẹ́ nítorí gbogbo ènìyàn.
2
Fún àwọn ọba, àti gbogbo àwọn tí ó wà ni ipò àṣẹ, kí a lè máa lo ayé wa ní àlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ pẹ̀lú nínú gbogbo ìwà-bí-Ọlọ́run àti ìwà mímọ́.
3
Nítorí èyí dára, ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run Olùgbàlà wa;
4
ẹni tí ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn ní ìgbàlà kí wọ́n sì wá sínú ìmọ̀ òtítọ́.
5
Nítorí Ọlọ́run kan ní ń bẹ, onílàjà kan pẹ̀lú láàrín Ọlọ́run àti ènìyàn, àní Kristi Jesu ọkùnrin náà.
6
Ẹni ti ó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà fún gbogbo ènìyàn—ẹ̀rí tí a fi fún ni ní àkókò tó yẹ.
7
Nítorí èyí tí a yàn mi ṣe oníwàásù, aposteli òtítọ́ ni èmi ń sọ, èmi kò ṣèké olùkọ́ àwọn aláìkọlà nínú ìgbàgbọ́ àti òtítọ́.
Settings