1 Samuẹli 9:1-14
1
Ará Benjamini kan wà, ẹni tí ó jẹ́ aláàánú ọlọ́rọ̀, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kiṣi, ọmọ Abieli, ọmọ Serori, ọmọ Bekorati, ọmọ Afiah ti Benjamini.
2
Ó ní ọmọkùnrin kan tí à ń pè ní Saulu, ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó yanjú, tí ó jẹ́ arẹwà, tí kò sí ẹni tó ní ẹwà jù ú lọ láàrín gbogbo àwọn ọmọ Israẹli—láti èjìká rẹ̀ lọ sí òkè, ó ga ju gbogbo àwọn ènìyàn tókù lọ.
3
Nísinsin yìí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó jẹ́ ti Kiṣi baba Saulu sì sọnù. Nígbà náà, Kiṣi sọ fún Saulu ọmọ rẹ̀ pé, “Mú ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ pẹ̀lú rẹ kí ẹ lọ láti wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.”
4
Bẹ́ẹ̀ ní ó kọjá láàrín àwọn ìlú olókè Efraimu, ó sì kọjá ní àyíká ilẹ̀ Ṣaliṣa, ṣùgbọ́n wọn kò rí wọn. Wọ́n sì kọjá lọ sí òpópó Ṣaalimu, ṣùgbọ́n àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kò sí níbẹ̀. Nígbà náà, ó kọjá ní agbègbè Benjamini, wọn kò sì rí wọn.
5
Nígbà tí wọ́n dé agbègbè Sufu, Saulu sọ fún ìránṣẹ́ tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí á padà sẹ́yìn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, baba mi yóò dá ìrònú rẹ̀ dúró nípa àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yóò sì bẹ̀rẹ̀ àníyàn nípa wa.”
6
Ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ náà fún un ní èsì pé, “Wò ó, ní inú ìlú yìí ọkùnrin ènìyàn Ọlọ́run kan wà; ó jẹ́ ẹni tí wọ́n ń bu ọlá fún, àti gbogbo ohun tí ó bá sọ ní ó máa ń jẹ́ òtítọ́. Jẹ́ kí á lọ síbẹ̀ nísinsin yìí, bóyá yóò sọ fún wá ọ̀nà tí a yóò gbà.”
7
Saulu sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀, “Tí àwa bá lọ, kín ni àwa lè fún ọkùnrin náà? Oúnjẹ inú àpò wa ti tán. A kò sì ní ẹ̀bùn láti mú lọ sọ́dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run. Kí ni a ní?”
8
Ìránṣẹ́ sì dá a lóhùn lẹ́ẹ̀kan sí i. “Wò ó,” ó wí pé, “Mo ní ìdámẹ́rin ṣékélì fàdákà lọ́wọ́. Èmi yóò fún ènìyàn Ọlọ́run náà kí ó lè fi ọ̀nà hàn wá.”
9
(Tẹ́lẹ̀ ní Israẹli tí ọkùnrin kan bá lọ béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run, yóò wí pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì náà,” nítorí àwọn alásọtẹ́lẹ̀ ìsinsin yìí ni wọ́n ń pè ní wòlíì).
10
Saulu sọ fún ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ pé ó dára, “Jẹ́ kí a lọ.” Wọ́n jáde lọ sí ìlú tí ènìyàn Ọlọ́run náà ń gbé.
11
Bí wọ́n ṣe ń lọ ní orí òkè sí ìlú náà, wọ́n pàdé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tí ó ń jáde í bọ̀ láti wá pọn omí. Wọ́n sì bi wọ́n, “Ṣé wòlíì náà wà níbí?”
12
“Ó wà,” wọ́n dáhùn. “Ó ń bẹ níwájú u yín, múra nísinsin yìí, ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wa lónìí ni, nítorí àwọn ènìyàn ní ẹbọ rírú ni ibi gíga.
13
Kété tí ẹ bá ti wọ ìlú, ẹ ó rí i kí ó tó lọ sí ibi gíga láti lọ jẹun. Àwọn ènìyàn kò sì ní bẹ̀rẹ̀ sí jẹun títí tí yóò fi dé. Torí ó gbọdọ̀ bùkún ẹbọ náà; lẹ́yìn náà, àwọn tí a pè yóò jẹun. Gòkè lọ nísinsin yìí, ó yẹ kí ẹ rí i ní àkókò yìí.”
14
Wọ́n gòkè lọ sí ìlú náà, bí wọ́n ti ń wọlé, níbẹ̀ ni Samuẹli, ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wọn bí ó ti ń lọ ibi gíga náà.
Settings