1 Samuẹli 15:28-35
28
Samuẹli sì wí fún un pé, “Olúwa ti fa ìjọba Israẹli ya kúrò lọ́wọ́ ọ̀ rẹ lónìí, ó sì ti fi fún aládùúgbò rẹ kan tí ó sàn jù ọ́ lọ.
29
Ẹni tí ó ń ṣe ògo Israẹli, kì í purọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í yí ọkàn rẹ̀ padà; nítorí kì í ṣe ènìyàn tí yóò yí ọkàn rẹ̀ padà.”
30
Saulu sì wí pé, “Èmi ti ṣẹ̀, ṣùgbọ́n jọ̀wọ́ bu ọlá fún mi níwájú àwọn àgbàgbà ènìyàn mi, àti níwájú u Israẹli, yípadà pẹ̀lú mi, kí èmi kí ó lè tẹríba fún Olúwa Ọlọ́run rẹ.”
31
Bẹ́ẹ̀ ni Samuẹli sì yípadà pẹ̀lú Saulu, Saulu sì sin Olúwa.
32
Nígbà náà ni Samuẹli wí pé, “Mú Agagi ọba àwọn ará Amaleki wá fún mi.” Agagi sì tọ̀ ọ́ wá ní ìgboyà pẹ̀lú èrò pé, “Nítòótọ́ ìkorò ikú ti kọjá.”
33
Ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé, “Bí idà rẹ ti sọ àwọn obìnrin di aláìní ọmọ bẹ́ẹ̀ ni ìyá rẹ yóò sì di aláìní ọmọ láàrín obìnrin.” Samuẹli sì pa Agagi níwájú Olúwa ni Gilgali.
34
Nígbà náà ni Samuẹli lọ sí Rama, Saulu sì gòkè lọ sí ilé e rẹ̀ ní Gibeah tí Saulu.
35
Samuẹli kò sì padà wá mọ́ láti wo Saulu títí ó fi di ọjọ́ ikú u rẹ̀, ṣùgbọ́n Samuẹli káàánú fún Saulu. Ó sì dun Olúwa pé ó fi Saulu jẹ ọba lórí Israẹli.
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings