1 Samuẹli 10:20-27
20
Nígbà tí Samuẹli mú gbogbo ẹ̀yà Israẹli súnmọ́ tòsí, ó yan ẹ̀yà Benjamini.
21
Ó kó ẹ̀yà Benjamini síwájú ní ìdílé ìdílé, a sì yan ìdílé Matiri. Ní ìparí a sì yan Saulu ọmọ Kiṣi. Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí wọ́n wá a, a kò rí i,
22
bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Olúwa pé, “Ṣé ọkùnrin náà ti wá sí bí ni?” Olúwa sì sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ láàrín àwọn ẹrù.”
23
Wọ́n sáré, wọ́n sì mú un jáde wá. Bí ó ti dúró láàrín àwọn ènìyàn, ó sì ga ju gbogbo àwọn tí ó kù lọ láti èjìká rẹ̀ sókè.
24
Samuẹli sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn pé, “Ṣé ẹ ti ri ọkùnrin tí Olúwa ti yàn? Kò sí ẹnìkan bí i rẹ̀ láàrín gbogbo àwọn ènìyàn.” Nígbà náà àwọn ènìyàn kígbe pé, “Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn!”
25
Samuẹli ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn àwọn ìlànà ìjọba. Ó kọ wọ́n sínú ìwé, ó sì fi lélẹ̀ níwájú Olúwa. Lẹ́yìn náà, Samuẹli tú àwọn ènìyàn ká olúkúlùkù sí ilé e rẹ̀.
26
Saulu náà padà sí ilé e rẹ̀ ní Gibeah. Àwọn akọni ọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi ọwọ́ tọ́ ọkàn wọ́n sì sìn ín.
27
Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Beliali wí pé, “Báwo ni ọkùnrin yìí yóò ti ṣe gbà wá?” Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọn kò sì mú ẹ̀bùn wá fún un, ṣùgbọ́n Saulu fọwọ́ lérán.
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings