1 Ọba 18:11-35
11
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ wí fún mi pé kí n lọ sọ́dọ̀ olúwa mi, kí n sì wí pé, ‘Elijah ń bẹ níhìn-ín.’
12
Èmi kò sì mọ ibi tí ẹ̀mí Olúwa yóò gbé ọ lọ nígbà tí mo bá fi ọ́ sílẹ̀. Bí mo bá lọ, tí mo sì sọ fún Ahabu, tí kò sì rí ọ, òun a sì pa mí. Síbẹ̀ èmi ìránṣẹ́ rẹ bẹ̀rù Olúwa láti ìgbà èwe mi wá.
13
Ṣé Olúwa mi kò ha ti gbọ́ ohun tí mo ṣe nígbà tí Jesebeli ń pa àwọn wòlíì Olúwa? Mo fi ọgọ́rùn-ún wòlíì Olúwa pamọ́ sínú ihò òkúta méjì, àràádọ́ta ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo sì fi omi àti oúnjẹ bọ́ wọn.
14
Ìwọ sì sọ fún mi nísinsin yìí pé, kí n tọ olúwa mi lọ pé, ‘Elijah ń bẹ níhìn-ín.’ Òun a sì pa mí!”
15
Elijah sì wí pé, “Bí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti wà, ẹni tí èmi ń sìn, nítòótọ́ èmi yóò fi ara mi hàn fún Ahabu lónìí.”
16
Bẹ́ẹ̀ ni Obadiah sì lọ láti pàdé Ahabu, ó sì sọ fún un, Ahabu sì lọ láti pàdé Elijah.
17
Nígbà tí Ahabu sì rí Elijah, ó sì wí fún un pé, “Ṣé ìwọ nìyìí, ìwọ tí ń yọ Israẹli lẹ́nu?”
18
Elijah sì dá a lóhùn pé, “Èmi kò yọ Israẹli lẹ́nu, bí kò ṣe ìwọ àti ilé baba rẹ. Ẹ ti kọ òfin Olúwa sílẹ̀, ẹ sì ń tọ Baali lẹ́yìn.
19
Nísinsin yìí kó gbogbo Israẹli jọ láti pàdé mi lórí òkè Karmeli. Àti kí o sì mú àádọ́ta lé ní irinwó (450) àwọn wòlíì Baali àti irinwó (400) àwọn wòlíì òrìṣà Aṣerah tí wọ́n ń jẹun ní tábìlì Jesebeli.”
20
Bẹ́ẹ̀ ni Ahabu ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ó sì kó àwọn wòlíì jọ sí orí òkè Karmeli.
21
Elijah sì lọ síwájú gbogbo àwọn ènìyàn, ó sì wí pé, “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin yóò máa ṣiyèméjì? Bí Olúwa bá ni Ọlọ́run, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ṣùgbọ́n bí Baali bá ni Ọlọ́run, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.” Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò sì wí ohun kan.
22
Nígbà náà ni Elijah wí fún wọn pé, “Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù ní wòlíì Olúwa, ṣùgbọ́n, àádọ́ta lé ní irinwó (450) ni wòlíì Baali.
23
Ẹ fún wa ní ẹgbọrọ akọ màlúù méjì. Jẹ́ kí wọn kí ó sì yan ẹgbọrọ akọ màlúù kan fún ara wọn, kí wọn kí ó sì gé e sí wẹ́wẹ́, kí wọn kí ó sì tò ó sí orí igi, kí wọn kí ó má ṣe fi iná sí i. Èmi yóò sì tún ẹgbọrọ akọ màlúù kejì ṣe, èmi yóò sì tò ó sórí igi, èmi kì yóò sì fi iná sí i.
24
Nígbà náà ẹ ó sì ké pe orúkọ àwọn Ọlọ́run yín, èmi yóò sì ké pe orúkọ Olúwa. Ọlọ́run náà tí ó fi iná dáhùn, òun ni Ọlọ́run.” Nígbà náà ni gbogbo àwọn ènìyàn náà sì wí pé, “Ohun tí ìwọ sọ dára.”
25
Elijah sì wí fún àwọn wòlíì Baali wí pé, “Ẹ yan ẹgbọrọ akọ màlúù kan fún ara yín, kí ẹ sì tètè kọ́ ṣe é, nítorí ẹ̀yin pọ̀. Ẹ ké pe orúkọ àwọn ọlọ́run yín, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe fi iná sí i.”
26
Nígbà náà ni wọ́n sì mú ẹgbọrọ akọ màlúù náà, tí a ti fi fún wọn, wọ́n sì ṣe é. Nígbà náà ni wọ́n sì ké pe orúkọ Baali láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán gangan wí pé, “Baali! Dá wa lóhùn!” Wọ́n sì ń kégbe. Ṣùgbọ́n kò sí ìdáhùn; kò sí ẹnìkan tí ó sì dáhùn. Wọ́n sì jó yí pẹpẹ náà ká, èyí tí wọ́n tẹ́.
27
Ní ọ̀sán gangan, Elijah bẹ̀rẹ̀ sí ń fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà ó sì wí pé, “Ẹ kígbe lóhùn rara Ọlọ́run sá à ni òun! Bóyá ó ń ṣe àṣàrò, tàbí kò ráyè, tàbí ó re àjò. Bóyá ó sùn, ó yẹ kí a jí i.”
28
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì kígbe lóhùn rara, wọ́n sì fi ọ̀bẹ àti ọ̀kọ̀ ya ara wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, títí tí ẹ̀jẹ̀ fi tú jáde ní ara wọn.
29
Nígbà tí ọjọ́ yẹ àtàrí, wọ́n sì ń fi òmùgọ̀ sọtẹ́lẹ̀ títí di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́, ṣùgbọ́n kò sí ohùn, kò sì ṣí ìdáhùn, kò sì ṣí ẹni tí ó kà á sí.
30
Nígbà náà ni Elijah wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ súnmọ́ mi.” Wọ́n sì súnmọ́ ọn, ó sì tún pẹpẹ Olúwa tí ó ti wó lulẹ̀ ṣe.
31
Elijah sì mú òkúta méjìlá, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ẹ̀yà ọmọ Jakọbu kan, ẹni tí ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ wá wí pé, “Israẹli ni orúkọ rẹ̀ yóò máa jẹ́.”
32
Ó sì tẹ́ pẹpẹ pẹ̀lú àwọn òkúta wọ̀nyí ní orúkọ Olúwa, ó sì wa yàrá yí pẹpẹ náà ká, tí ó lè gba ìwọ̀n òsùwọ̀n irúgbìn méjì.
33
Ó sì to igi náà dáradára, ó sì ké ẹgbọrọ akọ màlúù náà wẹ́wẹ́, ó sì tò ó sórí igi. Nígbà náà ni ó sì wí fún wọn wí pé, “Ẹ fi omi kún ìkòkò mẹ́rin, kí ẹ sì tu sórí ẹbọ sísun àti sórí igi náà.”
34
Ó sì wí pe, “Ẹ ṣe é ní ìgbà kejì.” Wọ́n sì ṣe é ní ìgbà kejì. Ó sì tún wí pé, “Ṣe é ní ìgbà kẹta.”
35
Omi náà sì sàn yí pẹpẹ náà ká, ó sì fi omi kún yàrá náà pẹ̀lú.
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings