Skip to content
1 Ọba 16:21-28

1 Ọba 16:21-28

21
Nígbà náà ní àwọn ènìyàn Israẹli dá sí méjì; apá kan wọn ń tọ Tibni ọmọ Ginati lẹ́yìn, láti fi í jẹ ọba, apá kan tókù sì ń tọ Omri lẹ́yìn.
22
Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tí ń tọ Omri lẹ́yìn borí àwọn tí ń tọ Tibni ọmọ Ginati lẹ́yìn. Bẹ́ẹ̀ ni Tibni kú, Omri sì jẹ ọba.
23
Ní ọdún kọkànlélọ́gbọ̀n Asa ọba Juda, Omri bẹ̀rẹ̀ sí ń jẹ ọba lórí Israẹli, ó sì jẹ ọba ní ọdún méjìlá, ọdún mẹ́fà ní Tirsa.
24
Ó sì ra òkè Samaria lọ́wọ́ Ṣemeri ní tálẹ́ǹtì méjì fàdákà, ó sì kọ́ ìlú sórí rẹ̀, ó sì pe ìlú náà ní Samaria, nípa orúkọ Ṣemeri, orúkọ ẹni tí ó kọ́kọ́ ni òkè náà.
25
Ṣùgbọ́n Omri sì ṣe búburú níwájú Olúwa, Ó sì ṣe búburú ju gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀ lọ.
26
Ó rìn ní gbogbo ọ̀nà Jeroboamu ọmọ Nebati àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó ti mú Israẹli ṣẹ̀, láti fi ohun asán wọn mú Olúwa, Ọlọ́run Israẹli bínú.
27
Ìyókù ìṣe àti ohun tí Omri ṣe, àti agbára rẹ tí ó fihàn, a kò ha kọ, wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Israẹli?
28
Omri sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ a sì sin ín ní Samaria. Ahabu ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options