1 Kọrinti 4:1-13
1
Nítorí náà, ṣe ló yẹ kí ènìyàn máa wò wá gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ àti ìríjú tí a fún ni oore-ọ̀fẹ́ láti mọ Kristi tí a fún ní oore-ọ̀fẹ́ láti mọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.
2
Òun kan náà tí ó tọ́ fún ìríjú, ni kí ó jẹ́ olóòtítọ́.
3
Ṣùgbọ́n ohun kíkíní ni fún mi pé, kí ẹ máa ṣe ìdájọ́ mi, tàbí kí a máa ṣe ìdájọ́ nípa ìdájọ́ ènìyàn; nítòótọ́, èmi kò tilẹ̀ dá ara mi lẹ́jọ́.
4
Nítorí tí ẹ̀rí ọkàn mi kò dá mi ní ẹ̀bi; ṣùgbọ́n a kò ti ipa èyí dá mi láre, ṣùgbọ́n Olúwa ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ mi.
5
Nítorí náà, kí ẹ má ṣe ṣe ìdájọ́ ohunkóhun, kí Olúwa tó padà dé, ẹni tí yóò mú ohunkóhun tí ó fi ara sin wá sí ìmọ́lẹ̀, tí yóò sì fi ìmọ̀ ọkàn ènìyàn hàn, nígbà náà ni olúkúlùkù yóò sì ní ìyìn tirẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
6
Ẹ kíyèsi i pé, mo ti fi ara mi àti Apollo ṣe àpẹẹrẹ nǹkan tí mo wí, pé kí ẹ̀yin lè ti ipa wa kọ́ láti máa ṣe ohun tí a ti kọ̀wé kọjá. “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe tìtorí ẹnìkan gbéraga sí ẹnìkejì.”
7
Nítorí ta ni ó mú ọ yàtọ̀ sí àwọn ẹlòmíràn? Kí ni ìwọ ni tí ìwọ kò rí gbà? Tí ìwọ ba sì gbà á, èétiṣe tí ìwọ fi ń halẹ̀ bí ẹni pé ìwọ kò gba á?
8
Ni báyìí ẹ ní ohun gbogbo tí ẹ ń fẹ́! Báyìí ẹ sì ti di ọlọ́rọ̀! Ẹ ti di ọba. Lójú yín, àwa ti di ẹni ẹ̀yìn. Ìbá dùn mọ́ mi tí ó bá jẹ́ pé lóòtítọ́ ni ẹ ti di ọba lórí ìtẹ́ yín: tí a ó sì máa jẹ ọba pẹ̀lú yín!
9
Nítorí mo rò pé Ọlọ́run ń fi àwa aposteli hàn ní ìkẹyìn bí ẹni tí a dá lẹ́bi ikú bí àwọn, nítorí tí a fi wá ṣe ìran wò fún àwọn ènìyàn àti àwọn angẹli àti gbogbo ayé.
10
Àwa jẹ́ aṣiwèrè nítorí Kristi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ọlọ́gbọ́n nínú Kristi! Àwa jẹ́ aláìlera, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ alágbára! Ẹ̀yin jẹ́ ẹni àyẹ́sí, àwa jẹ ẹni ẹ̀gàn!
11
Títí di wákàtí yìí ni a ń rìn kiri nínú ebi àti òǹgbẹ, a n wọ aṣọ àkísà, tí a sì ń lù wa, tí a kò sì ní ibùgbé kan.
12
Tí a ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́, wọn ń gàn wa, àwa ń súre, wọn ń ṣe inúnibíni sí wa, àwa ń forítì i.
13
Wọn ń kẹ́gàn wa, àwa ń bẹ̀bẹ̀. Títí di ìsinsin yìí ni a ti wà bí ohun ẹ̀gbin ayé, bí orí àkìtàn gbogbo ayé.
Settings