1 Kronika 6:63-81
63
Sebuluni àwọn ìran ọmọ Merari, ìdílé sí ìdílé, ní a pín ìlú méjìlá fún láti ẹ̀yà Reubeni, Gadi àti Sebuluni.
64
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli fún àwọn ará Lefi ní ìlú wọ̀nyí pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
65
Láti ẹ̀yà Juda, Simeoni àti Benjamini ni a pín ìlú tí a ti dárúkọ wọn sẹ́yìn fún.
66
Lára àwọn ìdílé Kohati ni a fún ní ìlú láti ẹ̀yà Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìlú agbègbè wọn.
67
Ní òkè orílẹ̀-èdè Efraimu, a fún wọn ní Ṣekemu (ìlú ńlá ti ààbò), àti Geseri
68
Jokimeamu, Beti-Horoni.
69
Aijaloni àti Gati-Rimoni lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
70
Pẹ̀lú láti apá ààbọ̀ ẹ̀yà Manase àwọn ọmọ Israẹli fún Aneri àti Bileamu lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn, fún ìyókù àwọn ìdílé Kohati.
71
Àwọn ará Gerṣoni gbà nǹkan wọ̀nyí. Láti ààbọ̀ ẹ̀yà ti Manase wọ́n gba Golani ní Baṣani àti pẹ̀lú Aṣtarotu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù wọn.
72
Láti ẹ̀yà Isakari wọ́n gba Kedeṣi, Daberati
73
Ramoti àti Anenu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
74
Láti ẹ̀yà Aṣeri wọ́n gba Maṣali, Abdoni,
75
Hukoki àti Rehobu lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
76
Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Naftali wọ́n gba Kedeṣi ní Galili, Hammoni àti Kiriataimu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
77
Àwọn ará Merari (ìyókù àwọn ará Lefi) gbà nǹkan wọ̀nyí. Láti ẹ̀yà Sebuluni wọ́n gba Jokneamu, Karta, Rimoni àti Tabori, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.
78
Láti ẹ̀yà Reubeni rékọjá Jordani ìlà-oòrùn Jeriko wọ́n gba Beseri nínú aginjù Jahisa,
79
Kedemoti àti Mefaati, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.
80
Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Gadi wọ́n gba Ramoti ní Gileadi Mahanaimu,
81
Heṣboni àti Jaseri lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.
Settings