Skip to content
1 Kronika 21:18-27

1 Kronika 21:18-27

18
Nígbà náà angẹli Olúwa náà pàṣẹ fún Gadi láti sọ fún Dafidi pé, kí Dafidi kí ó gòkè lọ, kí ó sì tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa lórí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi.
19
Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì gòkè lọ pẹ̀lú ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ tí Gadi ti sọ ní orúkọ Olúwa.
20
Nígbà tí Arauna sì ń pakà lọ́wọ́, ó sì yípadà ó sì rí angẹli; àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pa ará wọn mọ́.
21
Bí Dafidi sì ti dé ọ̀dọ̀ Arauna, Arauna sì wò, ó sì rí Dafidi, ó sì ti ibi ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ jáde, ó sì wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú Dafidi.
22
Dafidi sì wí fún Arauna pé, “Jẹ́ kí èmi kí ó ni ibi ìpakà rẹ kí èmi kí ó sì lè tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Olúwa, ìwọ ó sì fi fún mi ni iye owó rẹ̀ pípé, kí a lè dá àjàkálẹ̀-ààrùn dúró lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn.”
23
Arauna sì wí fún Dafidi pé, “Mú un fún ara rẹ, sì jẹ́ kí olúwa mi ọba kí ó ṣe ohun tí ó dára lójú rẹ̀. Wò ó, èmí yóò fún ọ ní àwọn màlúù fún ẹbọ sísun, àti ohun èlò ìpakà fún igi, àti ọkà fún ọrẹ oúnjẹ. Èmi yóò fun ọ ní gbogbo èyí.”
24
Ṣùgbọ́n ọba Dafidi dá Arauna lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n èmi yóò rà á ní iye owó rẹ̀ ní pípé, nítorí èmi kì yóò èyí tí ó jẹ́ tìrẹ fún Olúwa, tàbí láti rú ẹbọ sísun tí kò ná mi ní ohun kan.”
25
Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi san ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì wúrà fún Arauna nípa ìwọ̀n fún ibẹ̀ náà.
26
Dafidi sì tẹ́ pẹpẹ fún Olúwa níbẹ̀ ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ọpẹ́. Ó sì ké pe Olúwa, Olúwa sì fi iná dá a lóhùn láti òkè ọ̀run wá lórí pẹpẹ fún ẹbọ ọrẹ sísun.
27
Nígbà náà Olúwa sọ̀rọ̀ sí angẹli, ó sì gbé idà padà bọ̀ sínú àkọ̀ rẹ̀.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options