Skip to content
1 Kronika 2:3-15

1 Kronika 2:3-15

3
Àwọn ọmọ Juda: Eri, Onani àti Ṣela, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí ni wọ́n bí fún un láti ọ̀dọ̀ arábìnrin Kenaani, ọmọbìnrin Ṣua. Eri àkọ́bí Juda, ó sì burú ní ojú Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì pa á.
4
Tamari, aya ọmọbìnrin Juda, ó sì bí Peresi àti Sera sì ní ọmọ márùn-ún ní àpapọ̀.
5
Àwọn ọmọ Peresi: Hesroni àti Hamulu.
6
Àwọn ọmọ Sera: Simri, Etani, Hemani, Kalkoli àti Dara, gbogbo wọn jẹ́ márùn-ún.
7
Àwọn ọmọ Karmi: Akani, ẹni tí ó mú ìyọnu wá sórí Israẹli nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìfibú lórí mímú ohun ìyàsọ́tọ̀.
8
Àwọn ọmọ Etani: Asariah.
9
Àwọn ọmọ tí a bí fún Hesroni ni: Jerahmeeli, Ramu àti Kalebu.
10
Ramu sì ni baba Amminadabu, àti Amminadabu baba Nahiṣoni olórí àwọn ènìyàn Juda.
11
Nahiṣoni sì ni baba Salmoni, Salmoni ni baba Boasi,
12
Boasi baba Obedi àti Obedi baba Jese.
13
Jese sì ni baba Eliabu àkọ́bí rẹ̀; ọmọ ẹlẹ́ẹ̀kejì sì ni Abinadabu, ẹlẹ́ẹ̀kẹta ni Ṣimea,
14
ẹlẹ́ẹ̀kẹrin Netaneli, ẹlẹ́ẹ̀karùnún Raddai,
15
ẹlẹ́ẹ̀kẹfà Osemu àti ẹlẹ́ẹ̀keje Dafidi.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options