Skip to content
1 Kronika 2:3-8

1 Kronika 2:3-8

3
Àwọn ọmọ Juda: Eri, Onani àti Ṣela, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí ni wọ́n bí fún un láti ọ̀dọ̀ arábìnrin Kenaani, ọmọbìnrin Ṣua. Eri àkọ́bí Juda, ó sì burú ní ojú Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì pa á.
4
Tamari, aya ọmọbìnrin Juda, ó sì bí Peresi àti Sera sì ní ọmọ márùn-ún ní àpapọ̀.
5
Àwọn ọmọ Peresi: Hesroni àti Hamulu.
6
Àwọn ọmọ Sera: Simri, Etani, Hemani, Kalkoli àti Dara, gbogbo wọn jẹ́ márùn-ún.
7
Àwọn ọmọ Karmi: Akani, ẹni tí ó mú ìyọnu wá sórí Israẹli nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìfibú lórí mímú ohun ìyàsọ́tọ̀.
8
Àwọn ọmọ Etani: Asariah.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options