Skip to content

Saamu136

1
Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
2
Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run: nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
3
Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa, nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
4
Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
5
Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
6
Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
7
Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
8
Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
9
Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
10
Fún ẹni tí ó kọlu Ejibiti lára àwọn àkọ́bí wọn; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
11
Ó sì mú Israẹli jáde kúrò láàrín wọn; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
12
Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
13
Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
14
Ó sì mú Israẹli kọjá láàrín rẹ̀ nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
15
Ṣùgbọ́n ó bi Farao àti ogun rẹ̀ ṣubú nínú Òkun pupa; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
16
Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn rẹ̀ la aginjù já nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
17
Fún ẹni tí ó kọlu àwọn ọba ńlá; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
18
Ó sì pa àwọn ọba olókìkí nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
19
Sihoni, ọba àwọn ará Amori nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
20
Àti Ogu, ọba Baṣani; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
21
Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní, nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
22
Ìní fún Israẹli, ìránṣẹ́ rẹ̀, nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
23
Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
24
Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
25
Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbo nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
26
Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Use arrow keys to navigate
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options