- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Mika4
Listen to this chapter
0:00
0:00
Àwọn Idà Di Àgbẹ̀dẹ̀
1
Ní ọjọ́ ìkẹyìn a ó fi òkè ilé Olúwa lélẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ, àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ̀ sínú rẹ̀.
2
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò wá, wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa, àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu. Òun yóò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.” Òfin yóò jáde láti Sioni wá, àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu.
3
Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, yóò sì parí aáwọ̀ fún orílẹ̀-èdè alágbára jíjìn réré. Wọn yóò sì fi idà wọn rọ ohun èlò ìtulẹ̀ àti ọ̀kọ̀ wọn di dòjé orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.
4
Ṣùgbọ́n olúkúlùkù yóò jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, ẹnìkan kì yóò sì dẹ́rùbà wọ́n, nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ̀rọ̀.
5
Gbogbo àwọn ènìyàn ń rìn, olúkúlùkù ni orúkọ ọlọ́run tirẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò máa rìn ní orúkọ Olúwa. Ọlọ́run wa láé àti láéláé.
Ìmúpadàbọ̀sípò Àwọn Kùṣù
6
“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí, “Èmi yóò kó àwọn arọ jọ; èmi yóò sì ṣà àwọn tí a lé kúrò ní ìlú jọ, àti àwọn ẹni tí èmi ti pọ́n lójú.
7
Èmi yóò dá àwọn arọ sí fún èyí tókù, èmi yóò sì sọ àwọn tí a lé kúrò ní ìlú di orílẹ̀-èdè alágbára. Olúwa yóò sì jẹ ọba lórí wọn ní òkè ńlá Sioni láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
8
Ní ti ìwọ, ilé ìṣọ́ agbo àgùntàn, odi alágbára ọmọbìnrin Sioni, a ó mú ìjọba ìṣáájú padà bọ̀ sípò fún un yín; ìjọba yóò sì wà sí ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.”
Ìpọ́njú Ìsinsìnyí àti Ìgbèkùn Bábílónì
9
Kí ni ìwọ ha ń kígbe sókè sí nísinsin yìí? Ǹjẹ́ ìwọ kò ní ọba bí? Àwọn ìgbìmọ̀ rẹ ṣègbé bí? Nítorí ìrora ti dì ọ́ mú bí obìnrin tí ń rọbí.
10
Máa yí síyìn-ín sọ́hùn-ún nínú ìrora, ìwọ obìnrin Sioni, bí ẹni tí ń rọbí, nítorí nísinsin yìí ìwọ yóò jáde lọ kúrò ní ìlú, ìwọ yóò sì máa gbé inú igbó. Ìwọ yóò lọ sí Babeli; níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì ti rí ìgbàlà. Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ.
Ìṣẹ́gun Lórí Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ọ̀tá
11
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ Orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọ sí ọ. Wọ́n sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sọ ọ́ di àìmọ́, ẹ jẹ́ kí ojú wa kí ó wo Sioni!”
12
Ṣùgbọ́n wọn kò mọ èrò inú Olúwa; bẹ́ẹ̀ ni òye ìmọ̀ rẹ̀ kò yé wọn, nítorí ó ti kó wọn jọ bí i ìtí sínú ìpakà.
13
“Dìde, kí ó sì máa pa ọkà ìwọ ọmọbìnrin Sioni, nítorí èmi yóò sọ ìwo rẹ̀ di irin, èmi yóò sì sọ pátákò rẹ̀ di idẹ ìwọ yóò run ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè pátápátá.” Èmi yóò sì ya èrè wọn sọ́tọ̀ fún Olúwa àti ọrọ̀ wọn sí Olúwa gbogbo ayé.
Use ← → arrow keys to navigate
Settings
Reading Style
Typeface
Font Size px
Reading Width chars
Options
Study Note