Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Zur

6 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Orúkọ ọmọbìnrin Midiani náà tí a pa ní Kosbi ọmọbìnrin Suri, tí ṣe olóyè àwọn ẹ̀yà kan nínú ìdílé kan ní Midiani.

  2. nítorí pé wọ́n ṣe sí yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá nígbà tí wọ́n tàn yín nípa ìṣẹ̀lẹ̀ Peori, àti arábìnrin wọn Kosbi ọmọbìnrin ìjòyè Midiani kan, obìnrin tí a pa nígbà tí àjàkálẹ̀-ààrùn ṣẹlẹ̀ nítorí Peori.”

  3. Wọ́n sì pa àwọn ọba Midiani pẹ̀lú: àwọn ìyókù tí wọ́n pa lára wọn ni Efi, Rekemu, Suri àti Huri, àti Reba: ọba Midiani márùn-ún, wọ́n sì fi idà pa Balaamu ọmọ Beori.

  4. gbogbo ìlú tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti gbogbo agbègbè Sihoni ọba Amori, tí ó ṣe àkóso Heṣboni. Mose sì ti ṣẹ́gun rẹ̀ àti àwọn ọmọ ìjòyè Midiani, Efi, Rekemu, Suri, Huri àti Reba, àwọn ọmọ ọba pawọ́pọ̀ pẹ̀lú Sihoni tí ó gbé ilẹ̀ náà.

  5. àkọ́bí rẹ̀ a sì máa jẹ́ Abdoni wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Suri, Kiṣi, Baali, Neri, Nadabu,

  6. pẹ̀lú àkọ́bí ọmọkùnrin rẹ̀ jẹ́ Abdoni, tí wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Suri, Kiṣi, Baali, Neri, Nadabu.